Uploaded by AL Afiyyatullahi Yah Lateef

IWE ASIRI IRAWO EDE VOLUME {1}

advertisement
IWE ASIRI IRAWO EDA
IWE ASIRI IRAWO EDA
BY PROPHET-ADEJESU THE GRATEST
ADEPTUS TEL:09033632885.
 ASIRI IRAWO EDA BY PROPHET-ADEJESU
No art of this book may be reproduced,
stored in a retrieval system, or transmitted
in any form or by any means, electronic or
mechanic, including photocopy, recording
or by any information storage and retrieval
system, without the permission in
writing of the Publisher.
IRAWO EDA
1. (Jan. 20 - Feb. 18 - Aquarius - irawo Afefe)
2. (Feb. 19 - Mar. 20 - Pisces - irawo omi)
3. (Mar. 21 - April 19 - Aries - irawo ina)
4. (April. 20 - May 20 - Taurus - irawo Erupe)
5. (May 21 - June 20 - Gemini - irawo Afefe)
6. (June 21 - July 22 - Cancer - irawo omi)
7. (July 23 - Aug. 22 - Leo - irawo ina)
 ASIRI IRAWO EDA BY PROPHET-ADEJESU
8. (Aug. 23 - Sept. 22 - Virgo - irawo erupe)
9. (Sept. 23 - Oct. 22 - Libra - Irawo Afefe)
10. (Oct. 23 - Nov. 21 - Scorpio - irawo Omi)
11. (Nov. 22 - Dec. 21 - Sagittarius - irawo ina)
12. (Dec. 22 - Jan. 19 - Capricorn - irawo Erupe)
ASOTELE ATI IRAWO OJO IBI OMO
(1) Asotele nipa omo ti a ba bi osu kokan lati
January ti o fi de December. E o mo iru iwa ti
omo yio ma hu, ati awon akoko Pataki fun .
(2) ILERA:- E o mo iru aisan ti yio fe ma se
omo nyin, e o si mo bi e o ti se yara pa ina aisan
na ki o to din la, e o mo iru ohun ti o lee fa aisan
na ati ohun ti o ye ki e se.
(3) ISE: E o mo iru ise Pataki ti o dara ti o je ti
omo nyin, nipa bee, e o tete dari re si ona ise
 ASIRI IRAWO EDA BY PROPHET-ADEJESU
tire; eyi ko ni jeki e na owo lasan, ko si ni jeki
omo nyin na fi akoko sofo lori ise ti ki se ona re.
(4) IKILO:- Iru iwa ti ko dara ti omo yin ma
hu, e o mo o, e o tete gba iru iwa buburu be kuro
lowo re ati awon asiri Pataki miran.
(5) Afe ki o ye yin pe, gbogbo eniyan ti abi laiye
yi loni irawo kokan, gege bi Olorun ti se eto
re ni atetekose, ninu irawo na ni gbogbo
igbesi aiye olukulu wa, fun apere, ninu irawo
ti Jesu Kristi ni awon amoye ijosi ti ri asiri
igbesi aiye Jesu, tin won fi mo pe Eni Nla ni
Jesu se, ti won fi wa teriba fun:- (Matt.2:1-2)
Gbogbo ohun ti a ko sinu irawo ti Jesu, lo se mo
olara laiye (Daniel &:13-14) beni ohun ti o wa
ninu irawo ti olukuluku yio mo lara, irawo
olukuluku enikeni laiye yi ko si le pa a da nitori
ki se tadawa (ink) ati iwe lasan ni Olorun
fi ko kadara olukuluku, bikose ohun ijinle,
nitorina ni oro na fi so ninu Korinti Keji, Ori 3,
ese 3 bayi pe “ki ise eyiti a fi tadawa ko, bikose
Emi Olorun alaye, Eyi lo mu wa fi igboiya so
 ASIRI IRAWO EDA BY PROPHET-ADEJESU
gbolohun oro meta yipe “Omo eniyan nlo bi ati
ko iwe nipa tire”(Matt. 26:24) “irawo sa yato si
irawo li ogo”(1 Kor. 15:41) “Oluwa ti se ohun
gbogbo fun ipinnu re.
JANUARY(December 22JANUARY19) IRAWO IYEPE
Oruko irawo akoko yi ni “Carpricon
IRAWO IYEPE”
Omo ti a ba bi lati December 22 titi de
January 19 yio je eni ti yio ma ka nkan si
Pataki, oro die ni yio ma dun u, yio si ni itiju
je eni ti yio ma ka nkan si Pataki, oro die ni
yio ma dun u, yio si ni itiju, koni fe ma yoju
si ohun ti ko kan a, yio je oninu rere eniyan,
 ASIRI IRAWO EDA BY PROPHET-ADEJESU
ko ni tete je olowo titi yio fi lo idaji ojo ewe
re, sugbon ire mbe fun u lehin ola.
ILERA:- Awon aisan wonyi yio fe ma yo o
lenu bi eko ba tete mura si I, aisan giri,
Lakuregbe, Ile-tutu,Kuruna ati ehin didun,
ki o si ma sora nitori ifarapa.
ISE:- Awon ise ti o dara fun u ni wonyi, ise
birikila ati kontrakito, ki o se Mekaniki ati
orisirisi ise elero ati Motor, ise oselu tabi ise
agbe.
IKILO:- Mase je alagidi ati olori kunkun
eniyan,mase je anikanjopon, mase fi ikanju
gbeyawo, mase tete ma fi oro kekere se
ibinu, mase gbekele eniyan ju ara re lo,
mase yara mafi ise kekere sile lati lo se ise
nla, a o ni lati ro o dada, ma wo aso ti o dara
ti o si ba o lara mu, to ye o.
 ASIRI IRAWO EDA BY PROPHET-ADEJESU
FEBRUARY(January 20-February 18)
IRAWO AFEFE.
Oruko irawo akoko yi ni “Aquarius” Omo ti
a ba bi lati January 20 titi de Febuary 18,
yio kun fun ogbon, yio si mo eko pupo, bi a
ba to o si ona ile- eko yio dara fun pupo, yio
je eniyan jeje, yio si feran lati ma da si oro
ilu, yio ma fe ilosiwaju ibiti o ba wa, yo
mura lati tako enikeni ti o ba fe lodi si otito,
yio si feran orin didun, awon eniyan yio ma
gba oro re sodi nigba miran, yoo je alanu
eniyan ti yio si ma ran enikeni lowo.
ILERA:- Awon aisan wonyi ni yio fe ma
see, aisan inu eje, ara iwora, oyi irora
orikerike, ara isaka ati efori, lakuregbe ati
oju didun, nigbati o ba de idaji igbesi aiye
 ASIRI IRAWO EDA BY PROPHET-ADEJESU
re, ko o sora nigbana nitori aisan wonyi, ki
nwon ma ba lagbara lori re.
ISE:- Awon ise ti o dara fun u ni Nosi
(Nurse) tabi ise Dokita, ati egbogi tita, ise
ina waya (Electricity) ati ise akowe.
IKILO:- Mase lo siwaju lati wadi bi ohun
yio ti ri, mase je ari-teni-mo wi nikan, mase
jeki emi ole ba le o, bi idanwo ba de ba o,
mase ba ara je nitori ire ti o Nbo, bi o ba se
ileri fun eniyan gbiyanju lati mu u se, fun
ire re ni o, mase ya eniyan lowo ki o mase
bere Si ro ero giga lasan, bikose pe ki o tera
mo ise owore, bi o ba tesiwaju, Oowo re yio
te ife okan re.
 ASIRI IRAWO EDA BY PROPHET-ADEJESU
March- (February 19 March 20)
Oruko irawo akoko yi ni “Pisces”
IRAWO OMI.
Omo ti a ba bi lati Feburuary 19 titi de
March 20 yio je eniti o feran awon egbe re,
yio je olokan fifuye eniyan si enikeni, nigba
miran yio huwa (rere tabi buburu) ti on
papaa ko ro tele lati se, yio je eniti yio ma
gba imoran gbo ju o ti ye lo, yio ni ebun
opolo fun eko, bi o ba se ire nigba miran
nwon tun le ma da a lebi fun ire ti o se, yio
je eniti ko fe ba eniyan jiyan lori
ohunkohun, bi o ba se nse be pupo, awon
eniyan yio ma re je ti o ba ndake ju, yio je
 ASIRI IRAWO EDA BY PROPHET-ADEJESU
oloto eniyan ti o se gbekele ni ipokipo ti o
ba wa.
ILERA:- Aisan ti yio ma fe se e ni wonyi:
Iba, otutu, efori ataiya didun, aisan wewewe
wonyi yio ma se e ni omo owo, sugbon ki yio
ju be lo.
ISE:- Awon ise wonyi dara fun u, ise akowe
oti sise ati tita, ise oko oju omi, egbogi pipo
(Pharmacy ati ise Ojise Olorun).
IKILO:- Mase je alaroye eniyan, mase kun
bi owo re ko ba te ohun ti o nfe, mase je
oninakuna, mase gba gbogbo imoran
elomiran lati fi huwa, ma wadi fun 'ra re,
ohun ti o ba ye ki o soro le lori mase dake,
sora nitori awon eletan ore, mase fi inu han
eniti o ko mo inu re.
 ASIRI IRAWO EDA BY PROPHET-ADEJESU
APRIL:- (March 21- April-21)Oruko
Irawo akoko yi ni “Arise”IRAWO
IRAWO INA
Omo ti a ba bi lati March 21 titi de April 21
je omo ti yio ma huwa aigboran nigba
miran, agidi re le fi iya je e tabi se rere fun
nigba miran, asiki ko le po fun O to be ti o
ba nsise labe ase bikose ki on na je oga ise
fun 'rere, yio fe gba ija elomiran ja, eyi yio
ma fa ota fun u, mase kun fun wahala aseju
nibi ise ti ko ni lari.
ILERA:- Aisan ti yio fe ma se e ni, efori,
oju-didun, otutu iba ati oyi.
 ASIRI IRAWO EDA BY PROPHET-ADEJESU
ISE:-Awon ise ti o dara fun niwonyi:- ise
akowe Oja-tita, ati Mekaniki, ati are sise
gege bi Baba Wande.
IKILO:- Mase ba enikeni da ise po, mase fi
agidi taku sidi ise ti ko lere, mase jeki ija
onija di tire, mase sise gbagbe akoko ti o ye
lati fun ara re ni isinmi, mase jeki emi
igberaga ba le o, mase ri enikeni fin, mase
yaju si eniti o ju o lo, mase gbekele ero ara
re nikan lati ma huwa gege bi ife okan re
nigba gbogbo.
MAY-( ARIL20-MAY21)
Oruko irawo akoko yi ni “”Taurus
IRAWO ERUPE.
 ASIRI IRAWO EDA BY PROPHET-ADEJESU
Omo ti a ba bi lati April 20 titi de May 21,
yio je eniyan jeje,ti kii tete binu, sugbon
lekan ti ibinu re baru soke, ki yio tete gbo
ipe, yio feran ohun to ba lewa ati oso-ise, yio
si feran eran osin, bi ko ba sora obinrin ti ki
duro pe lodo oko ni yio ma fe sile, ti yio si
ma salo, yio 'lowo sugbon inakuna po fun.
ILERA:- Awon aisan ti yio fe se e ni ona
ofun didun, iwora, osi gbodo sora dada nipa
ohun mimu ati jije lode, ki o ma ba je pe
nibe ni won yio ti fi egbogi buburu si nkan
fun u je, ti yio se iku pa a.
ISE:- Ise ti o dara fun niwonyi:- Orisirisi ise
owo, Ile kiko (Building) ati Birikila, ise
agbe,ise iwe irohin ati ise onje siseta.
IKILO:- Mu suru dada, wadi dada ki o to
gbeyawo, mase na owoni inakuna, mase fi
ilera omo nikeji re na owo ni inakuna, mase
ko ise re ni abo, mase kun fun oti mimu, bi
eniyan ba ngbe o ga, sibe sora, nitoripe ota
 ASIRI IRAWO EDA BY PROPHET-ADEJESU
re mbe larin won, mase mu oti lile rara,
mase ba won ta tete nitori adanu.
JUNE:- (MAY21-JUNE 20)
Oruko irawo akoko yi ni “Gemini”IRAWO
AFEFE.
Omo ti a ba bi lati May 21 titi de June 20 yio
je eniti yio ma figbona okan tete gba nkan
mora sugbon ti ko nip e ki nkan na to su u,
yio je eniti ko ni ma mu ileri ti o ba se se,
ireti ayo wa fun, yio si ni apon ati agbara lati
se ohun ti inu re dun si yio je “ari yawo
ko iyale sile”eniyan.
ILERA:-Aisan ti yio fe ma se e ni Lakuregbe
irora lekokan ati otutu, ehin didun, ju
gbogbo re lo, ki o
 ASIRI IRAWO EDA BY PROPHET-ADEJESU
sora dada nitori isubu ati ipalara igba kokan
ti o lewu.
ISE:- Ise ti o dara fun u lati ma se ni
wonyi:Ise Oluko, ise Noosi tabi Dokita, ise
Oselu ati ise ti o faramo irin-ajo lilo.
IKILO:- Mase kanju se ohunkohun, mura
lati ni ifarada ni akoko wahala nitori ore ti
ombe lehin wahala na, bi iwo pelu eniyan ba
jo so oro, tabi se adehun, mura lati mu ileri
na se ki awon eniyan ma ba peo ni odale,
mase so ese kekere din la mo eniyan lowo,
mase fi igba gbogbo duro de iranlowo
eniyan.
JULY- (JUNE 21-JULY-22)
Oruko irawo akoko yi ni
“Canser”IRAWO OMI
 ASIRI IRAWO EDA BY PROPHET-ADEJESU
Omo ti a ba bi lati June 21 titi de July 22,
yio je ologbon omo, o je omo ti a gbodo
moju to dada lati igba omode lati to o si ona
rere, ki ole wulo ni dada lati igba omode lati
to o si ona rere, ki ole wulo ni igbesi aiye re,
nitoripe iwa buburu ti o ba bere si hu ni
igba omode, ki yio le fi sile ti o ba dagba, ki
eyi ma ba so di eniyan lasan lojo aiye re ati
nikehin ki o ma ba ke ami re kuru, yio je
eniti o le fi ibinu ba nkan je , yio je eniti
opolopo eniyan yio feran ti won yio si ma
telee bi ko ba fi iwa le won pada, yio feran
orin, yio si ni ebun orin pupo, yio si je lasiki
eniyan. ILERA:- Bi oru ban nmu u nigba
gbogbo, eyi yio ma aisan aa, nkan gbigbona
 ASIRI IRAWO EDA BY PROPHET-ADEJESU
pupo ko si ba a lara mu, o gbodo ma wa ibiti
afefe tutu ti nfe nigba gbogbo, aisan inu
rirun, irora ni orike-rike ara, ehin di-dun
ati efori wa fun.
ISE:- Ise ti o dara fun ni iwonyi; ise ero
lorisirisi ona EnGineering) ise ina iletiki
(Electrical work ise hotel, ati kowe oja tita).
KILO:- Mase se ilara enikeji re, masero ara
re pin bi idanwo a de ba o, mase ko ibawi,
mase nikan ma ro ero laigba imoran
elomiran se ogbon, mase fi ikugbu se idajo
nipa ohun kohun.
AUGUST:- (JULY23-AUGUST22)
Oruko irawo akoko yi ni “Leo”IRAWO INA
 ASIRI IRAWO EDA BY PROPHET-ADEJESU
Omo ti a ba bi lati July 23 titi de August 22,
yio je omo ologbon, sugbon yio je oninufufu eniyan,yio tete ma ka ese si eniyan lese,
ohun ti ko nilari ni yio ma titori re binu
nigba miran, sugbon oran ko nip e
tan lokan re, yio si ni emi idariji, yio ni ore
pup0, yio si je olorire, yio de ipo giga laiye
re, yio si ni opo owo, yio si ma na owo fun
anfani awon ore re ju ti ara re lo, yio si jo
ara re loju pupo.
ILERA:- Ki o sora, ki o si mura nitori ojudidun ti o le fo o loju, aisan miran ni iba,
iwora ati efori sugbon oju didun nikan soro
ju fun o
ISE:-Awon ise bi olopa ati ise sinima
(sinima) foto yiya, ise oluko, dara fun u ati
oja tita dara fun u.
IKILO:- Je alagbara, mase fa sehin ninu
idanwo rere, mase pe ohunkohun ni kekere
mase fi ikanju se ohunkohun, mase jafara
lati ma mu inu eniyan dun, eniti o ba wa
 ASIRI IRAWO EDA BY PROPHET-ADEJESU
ninu ibanuje, ki o mu inu re dun, nitoripe a
fun o ni ebun re. mase jiyan lori oro ti ko ni
lari, mase je alaroye, mase ma se ise re ni
abo, pari ise kan ki o to na owo le omiran.
SEPTEMBER-(AUGUST23SEPTEMBER 22)
Oruko irawo akoko yi ni “Virgo”
IRAWO IYEPE
Omo ti a ba bi lati August 23 titi de
September 22, yio je eniti o le sise pupo yio
si ni itara si ise a ba fun se, yio je oloto ati
olusin Olorun, yio ni opolopo lati ko eko,
yio si mo iwe dada, nigba miran yio huwa ti
o yato si iwa re tele nigba miran yio dake si
ohun ti ko ye ki odake si, aso funfun dara
fun u lati ma lo.
ILERA:- Omo ti a ba bi ninu osu yi ki
saisan ti o le tobee, Alafia sip o fun u, aisan
 ASIRI IRAWO EDA BY PROPHET-ADEJESU
ti ole ma se e nigba miran ni inu rerun,
iwora, efori, ati ehin didun.
ISE:- Bise ti o dara fuin u ni ise akowe,ise
iwe sise (Author) ise shop oja tita, ise noosi
(Nurse) ati ise Loya (Lawyer).
IKILO:- Mase mo ti ara re nikan, mase fi
iwa ibinu fufu leawon ore re. maser o pe
gbogbo eniyan ni eke, iwo yio fe ma je ajaki
ati ajeju onje ati ohun mimu, nitorina mase
je onje poju bi o ti ye lo ati nkan mimu.
Ebun ogbon ti Olorun fun o po, mase fi yaju
tabi gberaga si enikeji, bikose ki o wulo fun
gbogbo enia, bu ola fun eniti ola ye fun, eni
iwaju ni o, tesiwaju nigbagbogbo, mase jeki
elomiran gba ipo re, mase je omuti.
OCTOTOBER - (September 23October 22)
Oruko irawo akoko yi ni “Libra”
IRAWO AFEFE
 ASIRI IRAWO EDA BY PROPHET-ADEJESU
Omo ti a ba bi lati Sept. 23 titi de October
22 yio je eniti o ni ro'nu, ti ki tete binu, o je
eniti o se bada nkan po se, yio ma ko eniyan
mora, yio je eniti o le se idajo ododo. Yoo
feran aso wiwo ati oso sise.
ILERA:- Wahala aseju le ko aisan ba a, ki
ise eniti o le ma se ise alagbara ju bi o ti ye
lo, bi o ba nsise ki o rip e on simi lakoko ti o
ba ye fun isinmi, ki o si ma nibi ti afefe tutu
ba wa, nitoripe oru ati nkan gbona ko baa
mu, ki o kun fun isora ninu odun ti o ba
omo odun metadinlogbon, ki a ma ba fun u
ni nkan buburu je ninu onje lati owo ota.
ISE: Ko nin fe ma duro pe nibi ise kan, eyi
je ohun ti o le re sile, ise oluko (Teaching)
Oniwasu, Adajo ati Oselu dara fun u.
IKILO:- Mase si kuro nibikan laini idi
Pataki, toju ohunkohun ti se ti owo dada,
masese faji lakoko ise, ma wo aso ti o dara ti
o ba o lara mu, fi suru kun iwa re, nipa suru
ni iwo yio fi ma segun.
 ASIRI IRAWO EDA BY PROPHET-ADEJESU
NOVEMBER- (Octobe 23- November
21 )
Oruko irawo akoko yi ni “Scorpion”
IRAWO OMI
Omo ti a ba bui lati October 23 titi de
November 21 yio je eniti o le tenu mo oran
tio ba nfe yio si so o dija bi nwon ko ba eniti
ole tenu mo oran ti o ba nfe yio si so o dija
bi nwon ko ba gba tire, yio le soro pupo, yio
je le eniti o nfe ki ama yin on bi oba se nkan
rere, iro ko si lenu re, bi ibinu re ba de, ko ni
bikita fun enikeni.
ILERA:- Aisan ti yo ma yo o lenu ni iba
efori ati ara riro nigba miran, aisan ko si fun
0 tobe.
ISE:-Ise ti odara fun ni ise Noosi (Nurse)
tabi Dokita oti nigba miran, aisan ko si fun
tobe.
 ASIRI IRAWO EDA BY PROPHET-ADEJESU
IKILO:-Mase rope iwo nikan ni ologbon,
gba imoran elomiran yewo, o le wulo fun o,
rere ni ki o ma ro si ara re ati si elomiran,
ise ti o ye o lati se loni, mase so di ola, mase
feti si oro awon abanije, mase so awada oro
di ija, mase na inakuna, fi suru kun
iwa re, ma gbiyanju nigba gbogbo, owo re
yio sitee ohun rere ti o nfe.
DECEMBER:- (November 22December 21) Oruko irawo akoko yi ni
“Sagitarius”IRAWO INA.
Omo ti a ba bi lati November 22 titi de
December 21 yio je akikanju ati eniti o laya
ninu ohun gbogbo, ero rere ati ireti ohun
rere ati ohun giga ni ero re nigba gbogbo,
owo re yio si ma te ohun rere ti o nfe, yio je
oninu-fufu nigba miran, yio ma se bi eniti
ko ka nkan si tobe nigba miran, bi o ba ti
pinnu lokan re lati se nkankan, ko ni fe gbo
 ASIRI IRAWO EDA BY PROPHET-ADEJESU
alaye tabi imoran enikeni mo ko ni fe ma da
si oro ti ki ise tire, irin-ajo lilo ati idale
gbigbe yio se e ni anfani pupo, ko ni fe
ka elomiran si eniti o le nkan (dada ) gege bi
on, nigba miran ohun kekere ni yio ma so di
ibinu, ti yio si so die se mo eniyan, lowo
sugbon ibinu re ki I pe rara, ko si le di
eniyan sinu, yio korira ki elomiran ma
sólori tabi pase fun on, ko si ni fe lati ma
sise labe ase oga Kankan nitori ebun titayo
ti Eleda funu, eyiko ni jeki o beru enikeni a
fi eniti o ba fe bu ola fun o je eniti yio ma fa
opo eniyan mora,yio ma o pa ise kan ti
sapakan lati ráye se ekeji, yio je alanu
eniyan.
ILERA:- Awon aisan ti yio fe ma yo o lenu
niwon yi: iba lakuregbe, iwora, otutu, ki o si
sora nitori ifarapa kekere nipa ijafara, ko si
aisan lile fun rara, Alafia si po fun u.
ISE:- Awon
ise ti o dara fun u ni wonyi:- Ise
 ASIRI IRAWO EDA BY PROPHET-ADEJESU
Oniwasu, asaju Isin, Olorun Ise loya
(Lawyer) ise Oluko (Teacher) oselu, iwe
kiko, iwe tite, ati ise ti o le mu ki eniyan ma
lo kakiri larin opo eniyan.
IKILO:-Mase kanju nigba miran ju bi o ti ye
lo,mase ma pa ise kan Pataki ti sapakan lati
bere omiran laity pari ti isaju, mase foju
tinrin elomiran ti ko loa to o, mase je ki oro
kekere tete ma di ibinu re, mase tete ma ka
ese si eniyan lorun, mase jeki o ya o lenu
tabi dun o, bi awon eniyan ba gba oro re
s'odi nigba miran, mae ro pe gbogbo ire ti o
ba se ni nwon o fi ma yin o, mase kun fun
igberaga nitori ebun ti Eleda fun o.
ASOTELE OJO IBI OMO (SUN-SAT)
SUNDAY:- Omo ti a ba bi lojo yi yio je omo
Pataki ati olola yio si je elemi gigun ati
oninu rere
 ASIRI IRAWO EDA BY PROPHET-ADEJESU
MONDAY:- Omo ti a ba bi lojo yi ki yio ni
ilosiwaju to bi o ti nfe ni ibere aiye re, yio je
onirele ati oninu rere tobee ti awon eniyan
yio fi ma re je, igbehin aiye re yio dara fun u
ju isaju re lo
TUESDAY:- Omo ti a ba bi lojo yi yio je omo
lile ati obinufufu, bi o ba je okunrin ni yio
ma fe se ohun ti o lodi si ofin (bi a ko ba ri
eni ka pa re) nipa be yio fa ibi ara re, bi ko
ba sora iwa tire yio fa ijiya ati iku ojiji ba a
nikehin ojo aiye re. Sugbon won fera obirin,
obinrin won si feran okunrin sora fun isubu
nipa re.
WEDNESDAY:- Omo ti aba bi lojo yi yio ni
imo ati eko pupo, bi aba fi si ile-iwe yio mo
iwe pupo, omo na yio je Olokiki, ona ise
alakowe ni o dara ju fun u, bi o ba nko yio
tete ma mo o, sugbon ohun ti o dara ju fun
ona ti iwe.
THURSDAY:- Omo ti a ba bi ni ojo yi yio je
olori niigbesi ojo aiyere, yio je alasiki eniyan
 ASIRI IRAWO EDA BY PROPHET-ADEJESU
igbadun ati Alafia mbe fun u, yio si laiya,
sugbon ni fifara mo Olorun daradara ni ota
ki yio fi le yo o lenu.
FRIDAY:-omo ti a ba bi lojo yi yio je olokan
lile ati onijongbon, yio ma se ori re lopolopo
ni igbesi aiye re, yio si je elese pupo, yio je
oloro ki o to ku, yio laya, kosini fe teriba fun
elegbe re ki yio ri ohun ti o tobi ju u lo.
SATURDAY:- Omo ti a ba bi lojo yi yio ri
idanwo die, yio si ma ri ohun ibanuje ni
ibere igbe aiye re, yio si dese, yio si ma jiya,
sugbon nikehin yio di eniyan Olorun,
olufokansin, awon egbe re yio ma bu ola
fun, Olorun yio bukun, ni igbehin aiye re
yio di oloro.
ISE TI O DARAFUN OLUKULUKU
O ye ki a ma wadi ise Eleda yan fun wa ki a
to le ma dawole ise Kankan lati se, eyi ti ole
mu ki eniyan se asiki ati orire ninu ise ti o
 ASIRI IRAWO EDA BY PROPHET-ADEJESU
ban nse. Ki ise eniti o nfi agbara ati gbogbo
ipa sile nikan lo ni ilosiwaju ati orire lenu
ise bikose eniti oba nse ise ti ise tire, Olorun
ti se liana ise olokuluku sile fun.(Psalm
37:23 Jeremiah 10:23) Nitorina mase lo
agbara re lasan lori ise ti ko lere fun o, nitori
ki ise ise re, nitorina ni (Oniwasu 9:11) fi wi
bayi pe: Mo pada mo si ri labe orun pe ireije ki ise ti eniti o yara beeni ogun ki ise ti
alagbara, beNI onje ki ise to ologbon, beni
oro ki ise ti eni oye, be ni ojurere ki se ti
ologbo-inu, sugbon igba ati ese nse si
gbogbo won. Nitorina ope ni fun Oluwa ti o
fun wa ni ore- ofe ati imo yui ire awa omo
eniyan lati mo ise ti olukuluku eniyan ti a bi
ninu osu kan.
ENITI ABABI NINU OSU
JANUARY:- Ise ti o dara fun iru eniyan be
ni ise owo sise oja tita ise mekaniki
(Mechanic and Engineerin) Ise Motor ati
orisirisi ise ero, ise oselu Politican) ise abere
 ASIRI IRAWO EDA BY PROPHET-ADEJESU
lorisirisi osu yi ni ise aso orisirisi ona ati ise
aso orisi reran (Dress making) ise abere
lorisirisi ona ati ise onje sis eta, tabi ise
Hotel ile onje fun awon ero. Opolopo awon
ti a ba bi ninu osu yi yio feran irin-ajo lilo.
FEBRUARY:- Ise ti o dara ju fun iru eniyan
be ni ise egbogi-iwosan Nosi (Nurse) ise
dokita (Doctor) Agbejoro (Lawyer) ise orin
kiko tabi ise apinta (carpenter) Awon ti a ba
bi ninu osu yi a ma ni ebun opolopo pupo
fun eko won.
MARCH:-Gbogbo ise akowe ise omowe ló
dara fun eniti a ba bi ninu osu yi ati Oga ile
kiko (Architect) ise kontrakito (Contractor)
ise omo-ogun (Army) ati ise isin Olorun
lorisirisi ona.
APRIL:- Ise ti odara ju fun iru eniyan be ni
ise iwe kiko (writing )lorisirisi ona,ise
Organist ati are sise kiri (Operatic stage)
awon ti a ba bi ninu osu yi a ma je oloto enia
nibikibi tabi ninu ise ti won bawa, nwon se
 ASIRI IRAWO EDA BY PROPHET-ADEJESU
gbekele. MAY:- Awon ti a ba bi ninu osu yi a
n ma ni opolo (Brain) nwon a si ma ni imo
pupo nipa eko iwe lorisirisi, Orisirisi iseowo, ise ile-kiko, ise-ero (Building and
Engineering) dara fun won. Nwon a si ma je
alasodun eniyan.
JUNE:-Ise ti o dara ju fun iru eniyan be ni
ise Eko ijinle, ise oselu, ise alakoso opo enia
ise noosi (Nurse) taabi Dokita (Doctor),
Nwon a ma se orire ninu ise ni ilu ajeji,
nwon a ma feran ati ma rin irin ajo, ise oja
tita ati ise oluko (Teacher)dara fun won
Awon ti a ba bi ninu osu yi a ma lanu
enuyan loju, won a si ma feran awon
omode.
JULY:-Ise ti o dara ju fun iru eniyan be ni
ise ero lorisirisi on (Engineering) ise ina
Iletirika (Electrical works) ise owo orisirisi,
ise foto (Photograher) ati oja tita ninu (shop
keeper).
 ASIRI IRAWO EDA BY PROPHET-ADEJESU
AUGUST:- Awon ti a ba bi ninu opolopo ise
tin won ba dawole gegebi ebun ogbon ti
Olorun fun nwon. awon ise ti o tun dara fun
won julo ni ise Atuko (Sailor) tabi orisirisi
ise oko oju-omi, ise oja tita lorisiris, ise
onigbagbo (Auctioneer) ise agbe, ohun-osin
tita, ise Oluko (Teacher), ise awonle
(Surveyor) ati ise onje sise e ta.
SEPTEMBER:- Ise ti o dara ju fun iru
eniyan be ni ise Ijoba lorisirisi ona oja tita,
ise Dokita (Doctor) Ise Nosi (Nurse ise Loya
(Lawyer), ati ise Olukoni (Teacher).
OCTOBER :- Omo kurin ti a ba bi ninu osu
yi ko ni fe ma duro pe nibi ise kan, ki yio si
bikita tabi fóju si oro owo tobe, iru iwa ni yi
yio fe mu u rehin die ti ko ba yi pada, Ise ti o
dara fun won ni ise Olukoni ati ise ti o ba
fara mo irin-ajo lilo nigba gbogbo inu oko
oju-omi, nwon ko ni fe ma teriba pelu tulasi
fun enikeni, nwon a si tete ma di oga nibi
 ASIRI IRAWO EDA BY PROPHET-ADEJESU
ise, ise ti o dara fun omobinrin won ni ise
oja tita, onisowo ise akowe.
NOVEMBER:- Ise ti odara ju fun eniti a ba
bi ninu osu yi ise oniwasu nitoripe yio ni
ebun iwasu pupo, nwon a si ma se orire ati
asiki ninu ise tin won ban se awon ise ti o
tun dara fun won ni Ise Noosi (Nurse)
Dokita (Doctor), ise owo lorisiris, Ise iwe
kiko (writing ati akojo iwe) lorisiris ona,
nwon o si se asiki ati orire pupo nipa ise iwe
na.
DECEMBER:- Awon ti a ba bi ninu osu yi a
ma wulo pupo nwon a si ma ni ebun
orisirisi ise-owo, awon ise ti odara ju fun
won ni ise ero(Engineering) ise Mekaniki
(Mechanic) ise irohin Jounalist ati ise
akowe lorisirisi ona.
“ITUMO AMIN ATI APERE TI ANRETI”
Oplopo ami ati apere ti awa eniyan nri láiye
 ASIRI IRAWO EDA BY PROPHET-ADEJESU
yi ni o ni itumo, sugbo ki ise gbogbo won ni
oni itumo, tabi je Pataki, awon ti oni ni
itumo Pataki ni iwonyi:1. Bi atari re ba nhun o ju bi o ti ye lo; itumo
re nipe iwo yio bo sipo giga kan lojo aiye re
tabi laipe.
2. Bi ipenpeju oju otun ki o ri ore nipa iwo
yio ri ohun ti o dun moo, tabi ki o ri ore to ti
lo siidale lojo pipe, tabi ki o ta re pada wa di
ore re.
3. Bi ipenpe oju osi re ba nhun o pupo,
itumo re nipe iwo yio ri ohun ti ko dun moo,
bi oku ore re Pataki tabi isele miran ti o
buru.
4. Bi eti re ba nke gere, itumo re nip e iwo
yio gbo irohin ayo kan laipe.
5. Bi eti re osi ba nke gere, itumo re re nipe
iwo yio gbo irohin buburu kan laipe lati
okere.
 ASIRI IRAWO EDA BY PROPHET-ADEJESU
6. Bi eti osi re ban kun ti o ba npariwo,
itumo re enikan nsoro re lehin ni buburu.
7. Bi imure ba nhun o ju bi oti ye, itumo re
nipe oro ijongbon ati ibanuje ko jinna si o,
nitorina ma gbadura ki o si ma sora.
8. Bi ejika re otun bah un o, itumo re nipe
ohun kan yio bo sodo re, ti yio si je ohun
ayo.
9. Bi ejika re osi ba nhun o,itumo re nipe
nipe ohun kan yio bo sodo re ti se ohun
ijongbo, nitorina sora .
10. Bi atelewo re otun ba hun o, iwo yio ri
owo kan gba laipe.
11. Bi atelewo osi ba nhun o, iwo yio na owo
kan laipe ti ise inawo ti ko dun mo o.
12. Bi orunkun re otun ba nhuno, itumo re
nipe iwo yio bo si ipo titun miran ti o yato si
eyiti iwo ti wa tele, igba yio yi pada sir ere
fun o, ati pe iwo yio je olusin Olorun ju bi o
 ASIRI IRAWO EDA BY PROPHET-ADEJESU
ti je tele lo, emi Olorun yio ma gbile lokan
re.
13. Bi ikun (Inu) re ba nhun o, itumo re nipe
pe, o pe o si ibi ase onje kan laipe.
ITUMO AMI DUDU ARAENIYAN
1. Bi ami dudu ribiribi ti o han dada ba wa
ni iwaju ori eniyan lapa otun o fi han pe eni
na yio di oloro lojiji ni igbesi aiye re, okiki re
yio si kan.
2. Bi ami dudu ba wa loke ipenpeju oju
otun, o fihan pe eni na yio tete gbeyawo, eni
ti yio si fe yio si je olori're eniyan ati alasiki.
3. Bi ami dudu ba wa ni ereke apa otun, tabi
ti osi, o fihan pe eni na ki yio je oloro ju bi o
ti ye beni ki yo si je talaka ju bi o ti ye lo.
4. Bi ami dudu ba wa wa lori imu, o fihan pe
eni na yio ma se ori're ninu opolopo
idawole re.
5. Bi ami dudu ba wa lara ete ti oke tabi ti
isale, o fihan pe eni na yio fe ma se nkan ti o
 ASIRI IRAWO EDA BY PROPHET-ADEJESU
lewu, yio si je eniti o ni ife rere sieniyan, eyi
yio si ma fun u ni isegun lona re.
6. Bi amin dudu ba wa ni agbon eniyan o
fihan pe eni na yio je alasiki eniyan ati eni
giga.
7. Bi ami dudu ba wa ni ona ofun lode, o
fihan pe, o di igbati eni na ba se igbeyawo ki
asiki re to ma posii.
8. Bi ami dudu ba wa lara omu apa otun, o
fihan pe iresile yio de ba eni na lojiji ni sa
kan ni igbesi aiye re, omobirin ni yio si poju
ninu awon omo re.
9. Bi ami dudu ba wa lara omu apa osi, o
fihan pe eni na yio ma se ori're ati asiki ninu
idawole re, yio si je eniti o ni ife rere si
eniyan, omokurin ni yio si je eniti o ni ife
ree si eniyan, omokurin ni yio poju ninu
awon omo re.
10. Bi ami dudu ba wa ni okan aiya eniyan,
ofihan pe Alafia ati ori re yio po fun eni na.
 ASIRI IRAWO EDA BY PROPHET-ADEJESU
11. Bi ami dudu bawa lara itan ese otun
eniyan, o fihan pe ole ati alajeki ni eni na.
12. Bi ami dudu ba wa lara itan ese osi
ofihan pe eni na yio di oloro nikehin, yio si
se ori're nipa igbeyawo.
13. Bi ami dudu ba wa lara itan ese osi,
ofihan pe eni na yio se wahala die ni igbesi
aiye re, yio si je eniti awon enia ko kasi.
14. Bi ami dudu ba wa ni orokun ese otun, o
fihan pe eni na yio se ori're nipa igbeyawo,
sugbon yio ba isoro die pade ni igbesi aiye
re.
15. Bi ami dudu bawa ni orokun ese osi,
ofihan pe eni na yio je oni wadu-wadu ati
alainironu eniyan sugbon ni ikehin aiye re,
yio di eniyan pele ati oloto oniwa-rere.
AKIYESI:- Iru nkan wonyi je apa kan ninu
ohun ti eniyan npe ni kadara (Akosile ti
Olorun ko fun olukuluku eda) osi ye ki o
dawa loju pe, iru nkan be wa fun olukuluku
eniyan, eyi ti Olorun ti se liana ti Olokuluku
 ASIRI IRAWO EDA BY PROPHET-ADEJESU
sile fun u ti enikeni ko si le yi pada
(Owe20:24), Orin Da. 37:23 ati Jer. 10:23
IWE ASIRI IRAWO EDA
VOLUME [1] COMPLETE
BY PROHET-ADEJESU THE
GRATEST ADEPTUS
09033632885
WATCHOUT FOR PART [2]
 ASIRI IRAWO EDA BY PROPHET-ADEJESU
Download