IWE ASIRI IRAWO EDA IWE ASIRI IRAWO EDA BY PROPHET-ADEJESU THE GRATEST ADEPTUS TEL:09033632885. ASIRI IRAWO EDA BY PROPHET-ADEJESU No art of this book may be reproduced, stored in a retrieval system, or transmitted in any form or by any means, electronic or mechanic, including photocopy, recording or by any information storage and retrieval system, without the permission in writing of the Publisher. IRAWO EDA 1. (Jan. 20 - Feb. 18 - Aquarius - irawo Afefe) 2. (Feb. 19 - Mar. 20 - Pisces - irawo omi) 3. (Mar. 21 - April 19 - Aries - irawo ina) 4. (April. 20 - May 20 - Taurus - irawo Erupe) 5. (May 21 - June 20 - Gemini - irawo Afefe) 6. (June 21 - July 22 - Cancer - irawo omi) 7. (July 23 - Aug. 22 - Leo - irawo ina) ASIRI IRAWO EDA BY PROPHET-ADEJESU 8. (Aug. 23 - Sept. 22 - Virgo - irawo erupe) 9. (Sept. 23 - Oct. 22 - Libra - Irawo Afefe) 10. (Oct. 23 - Nov. 21 - Scorpio - irawo Omi) 11. (Nov. 22 - Dec. 21 - Sagittarius - irawo ina) 12. (Dec. 22 - Jan. 19 - Capricorn - irawo Erupe) ASOTELE ATI IRAWO OJO IBI OMO (1) Asotele nipa omo ti a ba bi osu kokan lati January ti o fi de December. E o mo iru iwa ti omo yio ma hu, ati awon akoko Pataki fun . (2) ILERA:- E o mo iru aisan ti yio fe ma se omo nyin, e o si mo bi e o ti se yara pa ina aisan na ki o to din la, e o mo iru ohun ti o lee fa aisan na ati ohun ti o ye ki e se. (3) ISE: E o mo iru ise Pataki ti o dara ti o je ti omo nyin, nipa bee, e o tete dari re si ona ise ASIRI IRAWO EDA BY PROPHET-ADEJESU tire; eyi ko ni jeki e na owo lasan, ko si ni jeki omo nyin na fi akoko sofo lori ise ti ki se ona re. (4) IKILO:- Iru iwa ti ko dara ti omo yin ma hu, e o mo o, e o tete gba iru iwa buburu be kuro lowo re ati awon asiri Pataki miran. (5) Afe ki o ye yin pe, gbogbo eniyan ti abi laiye yi loni irawo kokan, gege bi Olorun ti se eto re ni atetekose, ninu irawo na ni gbogbo igbesi aiye olukulu wa, fun apere, ninu irawo ti Jesu Kristi ni awon amoye ijosi ti ri asiri igbesi aiye Jesu, tin won fi mo pe Eni Nla ni Jesu se, ti won fi wa teriba fun:- (Matt.2:1-2) Gbogbo ohun ti a ko sinu irawo ti Jesu, lo se mo olara laiye (Daniel &:13-14) beni ohun ti o wa ninu irawo ti olukuluku yio mo lara, irawo olukuluku enikeni laiye yi ko si le pa a da nitori ki se tadawa (ink) ati iwe lasan ni Olorun fi ko kadara olukuluku, bikose ohun ijinle, nitorina ni oro na fi so ninu Korinti Keji, Ori 3, ese 3 bayi pe “ki ise eyiti a fi tadawa ko, bikose Emi Olorun alaye, Eyi lo mu wa fi igboiya so ASIRI IRAWO EDA BY PROPHET-ADEJESU gbolohun oro meta yipe “Omo eniyan nlo bi ati ko iwe nipa tire”(Matt. 26:24) “irawo sa yato si irawo li ogo”(1 Kor. 15:41) “Oluwa ti se ohun gbogbo fun ipinnu re. JANUARY(December 22JANUARY19) IRAWO IYEPE Oruko irawo akoko yi ni “Carpricon IRAWO IYEPE” Omo ti a ba bi lati December 22 titi de January 19 yio je eni ti yio ma ka nkan si Pataki, oro die ni yio ma dun u, yio si ni itiju je eni ti yio ma ka nkan si Pataki, oro die ni yio ma dun u, yio si ni itiju, koni fe ma yoju si ohun ti ko kan a, yio je oninu rere eniyan, ASIRI IRAWO EDA BY PROPHET-ADEJESU ko ni tete je olowo titi yio fi lo idaji ojo ewe re, sugbon ire mbe fun u lehin ola. ILERA:- Awon aisan wonyi yio fe ma yo o lenu bi eko ba tete mura si I, aisan giri, Lakuregbe, Ile-tutu,Kuruna ati ehin didun, ki o si ma sora nitori ifarapa. ISE:- Awon ise ti o dara fun u ni wonyi, ise birikila ati kontrakito, ki o se Mekaniki ati orisirisi ise elero ati Motor, ise oselu tabi ise agbe. IKILO:- Mase je alagidi ati olori kunkun eniyan,mase je anikanjopon, mase fi ikanju gbeyawo, mase tete ma fi oro kekere se ibinu, mase gbekele eniyan ju ara re lo, mase yara mafi ise kekere sile lati lo se ise nla, a o ni lati ro o dada, ma wo aso ti o dara ti o si ba o lara mu, to ye o. ASIRI IRAWO EDA BY PROPHET-ADEJESU FEBRUARY(January 20-February 18) IRAWO AFEFE. Oruko irawo akoko yi ni “Aquarius” Omo ti a ba bi lati January 20 titi de Febuary 18, yio kun fun ogbon, yio si mo eko pupo, bi a ba to o si ona ile- eko yio dara fun pupo, yio je eniyan jeje, yio si feran lati ma da si oro ilu, yio ma fe ilosiwaju ibiti o ba wa, yo mura lati tako enikeni ti o ba fe lodi si otito, yio si feran orin didun, awon eniyan yio ma gba oro re sodi nigba miran, yoo je alanu eniyan ti yio si ma ran enikeni lowo. ILERA:- Awon aisan wonyi ni yio fe ma see, aisan inu eje, ara iwora, oyi irora orikerike, ara isaka ati efori, lakuregbe ati oju didun, nigbati o ba de idaji igbesi aiye ASIRI IRAWO EDA BY PROPHET-ADEJESU re, ko o sora nigbana nitori aisan wonyi, ki nwon ma ba lagbara lori re. ISE:- Awon ise ti o dara fun u ni Nosi (Nurse) tabi ise Dokita, ati egbogi tita, ise ina waya (Electricity) ati ise akowe. IKILO:- Mase lo siwaju lati wadi bi ohun yio ti ri, mase je ari-teni-mo wi nikan, mase jeki emi ole ba le o, bi idanwo ba de ba o, mase ba ara je nitori ire ti o Nbo, bi o ba se ileri fun eniyan gbiyanju lati mu u se, fun ire re ni o, mase ya eniyan lowo ki o mase bere Si ro ero giga lasan, bikose pe ki o tera mo ise owore, bi o ba tesiwaju, Oowo re yio te ife okan re. ASIRI IRAWO EDA BY PROPHET-ADEJESU March- (February 19 March 20) Oruko irawo akoko yi ni “Pisces” IRAWO OMI. Omo ti a ba bi lati Feburuary 19 titi de March 20 yio je eniti o feran awon egbe re, yio je olokan fifuye eniyan si enikeni, nigba miran yio huwa (rere tabi buburu) ti on papaa ko ro tele lati se, yio je eniti yio ma gba imoran gbo ju o ti ye lo, yio ni ebun opolo fun eko, bi o ba se ire nigba miran nwon tun le ma da a lebi fun ire ti o se, yio je eniti ko fe ba eniyan jiyan lori ohunkohun, bi o ba se nse be pupo, awon eniyan yio ma re je ti o ba ndake ju, yio je ASIRI IRAWO EDA BY PROPHET-ADEJESU oloto eniyan ti o se gbekele ni ipokipo ti o ba wa. ILERA:- Aisan ti yio ma fe se e ni wonyi: Iba, otutu, efori ataiya didun, aisan wewewe wonyi yio ma se e ni omo owo, sugbon ki yio ju be lo. ISE:- Awon ise wonyi dara fun u, ise akowe oti sise ati tita, ise oko oju omi, egbogi pipo (Pharmacy ati ise Ojise Olorun). IKILO:- Mase je alaroye eniyan, mase kun bi owo re ko ba te ohun ti o nfe, mase je oninakuna, mase gba gbogbo imoran elomiran lati fi huwa, ma wadi fun 'ra re, ohun ti o ba ye ki o soro le lori mase dake, sora nitori awon eletan ore, mase fi inu han eniti o ko mo inu re. ASIRI IRAWO EDA BY PROPHET-ADEJESU APRIL:- (March 21- April-21)Oruko Irawo akoko yi ni “Arise”IRAWO IRAWO INA Omo ti a ba bi lati March 21 titi de April 21 je omo ti yio ma huwa aigboran nigba miran, agidi re le fi iya je e tabi se rere fun nigba miran, asiki ko le po fun O to be ti o ba nsise labe ase bikose ki on na je oga ise fun 'rere, yio fe gba ija elomiran ja, eyi yio ma fa ota fun u, mase kun fun wahala aseju nibi ise ti ko ni lari. ILERA:- Aisan ti yio fe ma se e ni, efori, oju-didun, otutu iba ati oyi. ASIRI IRAWO EDA BY PROPHET-ADEJESU ISE:-Awon ise ti o dara fun niwonyi:- ise akowe Oja-tita, ati Mekaniki, ati are sise gege bi Baba Wande. IKILO:- Mase ba enikeni da ise po, mase fi agidi taku sidi ise ti ko lere, mase jeki ija onija di tire, mase sise gbagbe akoko ti o ye lati fun ara re ni isinmi, mase jeki emi igberaga ba le o, mase ri enikeni fin, mase yaju si eniti o ju o lo, mase gbekele ero ara re nikan lati ma huwa gege bi ife okan re nigba gbogbo. MAY-( ARIL20-MAY21) Oruko irawo akoko yi ni “”Taurus IRAWO ERUPE. ASIRI IRAWO EDA BY PROPHET-ADEJESU Omo ti a ba bi lati April 20 titi de May 21, yio je eniyan jeje,ti kii tete binu, sugbon lekan ti ibinu re baru soke, ki yio tete gbo ipe, yio feran ohun to ba lewa ati oso-ise, yio si feran eran osin, bi ko ba sora obinrin ti ki duro pe lodo oko ni yio ma fe sile, ti yio si ma salo, yio 'lowo sugbon inakuna po fun. ILERA:- Awon aisan ti yio fe se e ni ona ofun didun, iwora, osi gbodo sora dada nipa ohun mimu ati jije lode, ki o ma ba je pe nibe ni won yio ti fi egbogi buburu si nkan fun u je, ti yio se iku pa a. ISE:- Ise ti o dara fun niwonyi:- Orisirisi ise owo, Ile kiko (Building) ati Birikila, ise agbe,ise iwe irohin ati ise onje siseta. IKILO:- Mu suru dada, wadi dada ki o to gbeyawo, mase na owoni inakuna, mase fi ilera omo nikeji re na owo ni inakuna, mase ko ise re ni abo, mase kun fun oti mimu, bi eniyan ba ngbe o ga, sibe sora, nitoripe ota ASIRI IRAWO EDA BY PROPHET-ADEJESU re mbe larin won, mase mu oti lile rara, mase ba won ta tete nitori adanu. JUNE:- (MAY21-JUNE 20) Oruko irawo akoko yi ni “Gemini”IRAWO AFEFE. Omo ti a ba bi lati May 21 titi de June 20 yio je eniti yio ma figbona okan tete gba nkan mora sugbon ti ko nip e ki nkan na to su u, yio je eniti ko ni ma mu ileri ti o ba se se, ireti ayo wa fun, yio si ni apon ati agbara lati se ohun ti inu re dun si yio je “ari yawo ko iyale sile”eniyan. ILERA:-Aisan ti yio fe ma se e ni Lakuregbe irora lekokan ati otutu, ehin didun, ju gbogbo re lo, ki o ASIRI IRAWO EDA BY PROPHET-ADEJESU sora dada nitori isubu ati ipalara igba kokan ti o lewu. ISE:- Ise ti o dara fun u lati ma se ni wonyi:Ise Oluko, ise Noosi tabi Dokita, ise Oselu ati ise ti o faramo irin-ajo lilo. IKILO:- Mase kanju se ohunkohun, mura lati ni ifarada ni akoko wahala nitori ore ti ombe lehin wahala na, bi iwo pelu eniyan ba jo so oro, tabi se adehun, mura lati mu ileri na se ki awon eniyan ma ba peo ni odale, mase so ese kekere din la mo eniyan lowo, mase fi igba gbogbo duro de iranlowo eniyan. JULY- (JUNE 21-JULY-22) Oruko irawo akoko yi ni “Canser”IRAWO OMI ASIRI IRAWO EDA BY PROPHET-ADEJESU Omo ti a ba bi lati June 21 titi de July 22, yio je ologbon omo, o je omo ti a gbodo moju to dada lati igba omode lati to o si ona rere, ki ole wulo ni dada lati igba omode lati to o si ona rere, ki ole wulo ni igbesi aiye re, nitoripe iwa buburu ti o ba bere si hu ni igba omode, ki yio le fi sile ti o ba dagba, ki eyi ma ba so di eniyan lasan lojo aiye re ati nikehin ki o ma ba ke ami re kuru, yio je eniti o le fi ibinu ba nkan je , yio je eniti opolopo eniyan yio feran ti won yio si ma telee bi ko ba fi iwa le won pada, yio feran orin, yio si ni ebun orin pupo, yio si je lasiki eniyan. ILERA:- Bi oru ban nmu u nigba gbogbo, eyi yio ma aisan aa, nkan gbigbona ASIRI IRAWO EDA BY PROPHET-ADEJESU pupo ko si ba a lara mu, o gbodo ma wa ibiti afefe tutu ti nfe nigba gbogbo, aisan inu rirun, irora ni orike-rike ara, ehin di-dun ati efori wa fun. ISE:- Ise ti o dara fun ni iwonyi; ise ero lorisirisi ona EnGineering) ise ina iletiki (Electrical work ise hotel, ati kowe oja tita). KILO:- Mase se ilara enikeji re, masero ara re pin bi idanwo a de ba o, mase ko ibawi, mase nikan ma ro ero laigba imoran elomiran se ogbon, mase fi ikugbu se idajo nipa ohun kohun. AUGUST:- (JULY23-AUGUST22) Oruko irawo akoko yi ni “Leo”IRAWO INA ASIRI IRAWO EDA BY PROPHET-ADEJESU Omo ti a ba bi lati July 23 titi de August 22, yio je omo ologbon, sugbon yio je oninufufu eniyan,yio tete ma ka ese si eniyan lese, ohun ti ko nilari ni yio ma titori re binu nigba miran, sugbon oran ko nip e tan lokan re, yio si ni emi idariji, yio ni ore pup0, yio si je olorire, yio de ipo giga laiye re, yio si ni opo owo, yio si ma na owo fun anfani awon ore re ju ti ara re lo, yio si jo ara re loju pupo. ILERA:- Ki o sora, ki o si mura nitori ojudidun ti o le fo o loju, aisan miran ni iba, iwora ati efori sugbon oju didun nikan soro ju fun o ISE:-Awon ise bi olopa ati ise sinima (sinima) foto yiya, ise oluko, dara fun u ati oja tita dara fun u. IKILO:- Je alagbara, mase fa sehin ninu idanwo rere, mase pe ohunkohun ni kekere mase fi ikanju se ohunkohun, mase jafara lati ma mu inu eniyan dun, eniti o ba wa ASIRI IRAWO EDA BY PROPHET-ADEJESU ninu ibanuje, ki o mu inu re dun, nitoripe a fun o ni ebun re. mase jiyan lori oro ti ko ni lari, mase je alaroye, mase ma se ise re ni abo, pari ise kan ki o to na owo le omiran. SEPTEMBER-(AUGUST23SEPTEMBER 22) Oruko irawo akoko yi ni “Virgo” IRAWO IYEPE Omo ti a ba bi lati August 23 titi de September 22, yio je eniti o le sise pupo yio si ni itara si ise a ba fun se, yio je oloto ati olusin Olorun, yio ni opolopo lati ko eko, yio si mo iwe dada, nigba miran yio huwa ti o yato si iwa re tele nigba miran yio dake si ohun ti ko ye ki odake si, aso funfun dara fun u lati ma lo. ILERA:- Omo ti a ba bi ninu osu yi ki saisan ti o le tobee, Alafia sip o fun u, aisan ASIRI IRAWO EDA BY PROPHET-ADEJESU ti ole ma se e nigba miran ni inu rerun, iwora, efori, ati ehin didun. ISE:- Bise ti o dara fuin u ni ise akowe,ise iwe sise (Author) ise shop oja tita, ise noosi (Nurse) ati ise Loya (Lawyer). IKILO:- Mase mo ti ara re nikan, mase fi iwa ibinu fufu leawon ore re. maser o pe gbogbo eniyan ni eke, iwo yio fe ma je ajaki ati ajeju onje ati ohun mimu, nitorina mase je onje poju bi o ti ye lo ati nkan mimu. Ebun ogbon ti Olorun fun o po, mase fi yaju tabi gberaga si enikeji, bikose ki o wulo fun gbogbo enia, bu ola fun eniti ola ye fun, eni iwaju ni o, tesiwaju nigbagbogbo, mase jeki elomiran gba ipo re, mase je omuti. OCTOTOBER - (September 23October 22) Oruko irawo akoko yi ni “Libra” IRAWO AFEFE ASIRI IRAWO EDA BY PROPHET-ADEJESU Omo ti a ba bi lati Sept. 23 titi de October 22 yio je eniti o ni ro'nu, ti ki tete binu, o je eniti o se bada nkan po se, yio ma ko eniyan mora, yio je eniti o le se idajo ododo. Yoo feran aso wiwo ati oso sise. ILERA:- Wahala aseju le ko aisan ba a, ki ise eniti o le ma se ise alagbara ju bi o ti ye lo, bi o ba nsise ki o rip e on simi lakoko ti o ba ye fun isinmi, ki o si ma nibi ti afefe tutu ba wa, nitoripe oru ati nkan gbona ko baa mu, ki o kun fun isora ninu odun ti o ba omo odun metadinlogbon, ki a ma ba fun u ni nkan buburu je ninu onje lati owo ota. ISE: Ko nin fe ma duro pe nibi ise kan, eyi je ohun ti o le re sile, ise oluko (Teaching) Oniwasu, Adajo ati Oselu dara fun u. IKILO:- Mase si kuro nibikan laini idi Pataki, toju ohunkohun ti se ti owo dada, masese faji lakoko ise, ma wo aso ti o dara ti o ba o lara mu, fi suru kun iwa re, nipa suru ni iwo yio fi ma segun. ASIRI IRAWO EDA BY PROPHET-ADEJESU NOVEMBER- (Octobe 23- November 21 ) Oruko irawo akoko yi ni “Scorpion” IRAWO OMI Omo ti a ba bui lati October 23 titi de November 21 yio je eniti o le tenu mo oran tio ba nfe yio si so o dija bi nwon ko ba eniti ole tenu mo oran ti o ba nfe yio si so o dija bi nwon ko ba gba tire, yio le soro pupo, yio je le eniti o nfe ki ama yin on bi oba se nkan rere, iro ko si lenu re, bi ibinu re ba de, ko ni bikita fun enikeni. ILERA:- Aisan ti yo ma yo o lenu ni iba efori ati ara riro nigba miran, aisan ko si fun 0 tobe. ISE:-Ise ti odara fun ni ise Noosi (Nurse) tabi Dokita oti nigba miran, aisan ko si fun tobe. ASIRI IRAWO EDA BY PROPHET-ADEJESU IKILO:-Mase rope iwo nikan ni ologbon, gba imoran elomiran yewo, o le wulo fun o, rere ni ki o ma ro si ara re ati si elomiran, ise ti o ye o lati se loni, mase so di ola, mase feti si oro awon abanije, mase so awada oro di ija, mase na inakuna, fi suru kun iwa re, ma gbiyanju nigba gbogbo, owo re yio sitee ohun rere ti o nfe. DECEMBER:- (November 22December 21) Oruko irawo akoko yi ni “Sagitarius”IRAWO INA. Omo ti a ba bi lati November 22 titi de December 21 yio je akikanju ati eniti o laya ninu ohun gbogbo, ero rere ati ireti ohun rere ati ohun giga ni ero re nigba gbogbo, owo re yio si ma te ohun rere ti o nfe, yio je oninu-fufu nigba miran, yio ma se bi eniti ko ka nkan si tobe nigba miran, bi o ba ti pinnu lokan re lati se nkankan, ko ni fe gbo ASIRI IRAWO EDA BY PROPHET-ADEJESU alaye tabi imoran enikeni mo ko ni fe ma da si oro ti ki ise tire, irin-ajo lilo ati idale gbigbe yio se e ni anfani pupo, ko ni fe ka elomiran si eniti o le nkan (dada ) gege bi on, nigba miran ohun kekere ni yio ma so di ibinu, ti yio si so die se mo eniyan, lowo sugbon ibinu re ki I pe rara, ko si le di eniyan sinu, yio korira ki elomiran ma sólori tabi pase fun on, ko si ni fe lati ma sise labe ase oga Kankan nitori ebun titayo ti Eleda funu, eyiko ni jeki o beru enikeni a fi eniti o ba fe bu ola fun o je eniti yio ma fa opo eniyan mora,yio ma o pa ise kan ti sapakan lati ráye se ekeji, yio je alanu eniyan. ILERA:- Awon aisan ti yio fe ma yo o lenu niwon yi: iba lakuregbe, iwora, otutu, ki o si sora nitori ifarapa kekere nipa ijafara, ko si aisan lile fun rara, Alafia si po fun u. ISE:- Awon ise ti o dara fun u ni wonyi:- Ise ASIRI IRAWO EDA BY PROPHET-ADEJESU Oniwasu, asaju Isin, Olorun Ise loya (Lawyer) ise Oluko (Teacher) oselu, iwe kiko, iwe tite, ati ise ti o le mu ki eniyan ma lo kakiri larin opo eniyan. IKILO:-Mase kanju nigba miran ju bi o ti ye lo,mase ma pa ise kan Pataki ti sapakan lati bere omiran laity pari ti isaju, mase foju tinrin elomiran ti ko loa to o, mase je ki oro kekere tete ma di ibinu re, mase tete ma ka ese si eniyan lorun, mase jeki o ya o lenu tabi dun o, bi awon eniyan ba gba oro re s'odi nigba miran, mae ro pe gbogbo ire ti o ba se ni nwon o fi ma yin o, mase kun fun igberaga nitori ebun ti Eleda fun o. ASOTELE OJO IBI OMO (SUN-SAT) SUNDAY:- Omo ti a ba bi lojo yi yio je omo Pataki ati olola yio si je elemi gigun ati oninu rere ASIRI IRAWO EDA BY PROPHET-ADEJESU MONDAY:- Omo ti a ba bi lojo yi ki yio ni ilosiwaju to bi o ti nfe ni ibere aiye re, yio je onirele ati oninu rere tobee ti awon eniyan yio fi ma re je, igbehin aiye re yio dara fun u ju isaju re lo TUESDAY:- Omo ti a ba bi lojo yi yio je omo lile ati obinufufu, bi o ba je okunrin ni yio ma fe se ohun ti o lodi si ofin (bi a ko ba ri eni ka pa re) nipa be yio fa ibi ara re, bi ko ba sora iwa tire yio fa ijiya ati iku ojiji ba a nikehin ojo aiye re. Sugbon won fera obirin, obinrin won si feran okunrin sora fun isubu nipa re. WEDNESDAY:- Omo ti aba bi lojo yi yio ni imo ati eko pupo, bi aba fi si ile-iwe yio mo iwe pupo, omo na yio je Olokiki, ona ise alakowe ni o dara ju fun u, bi o ba nko yio tete ma mo o, sugbon ohun ti o dara ju fun ona ti iwe. THURSDAY:- Omo ti a ba bi ni ojo yi yio je olori niigbesi ojo aiyere, yio je alasiki eniyan ASIRI IRAWO EDA BY PROPHET-ADEJESU igbadun ati Alafia mbe fun u, yio si laiya, sugbon ni fifara mo Olorun daradara ni ota ki yio fi le yo o lenu. FRIDAY:-omo ti a ba bi lojo yi yio je olokan lile ati onijongbon, yio ma se ori re lopolopo ni igbesi aiye re, yio si je elese pupo, yio je oloro ki o to ku, yio laya, kosini fe teriba fun elegbe re ki yio ri ohun ti o tobi ju u lo. SATURDAY:- Omo ti a ba bi lojo yi yio ri idanwo die, yio si ma ri ohun ibanuje ni ibere igbe aiye re, yio si dese, yio si ma jiya, sugbon nikehin yio di eniyan Olorun, olufokansin, awon egbe re yio ma bu ola fun, Olorun yio bukun, ni igbehin aiye re yio di oloro. ISE TI O DARAFUN OLUKULUKU O ye ki a ma wadi ise Eleda yan fun wa ki a to le ma dawole ise Kankan lati se, eyi ti ole mu ki eniyan se asiki ati orire ninu ise ti o ASIRI IRAWO EDA BY PROPHET-ADEJESU ban nse. Ki ise eniti o nfi agbara ati gbogbo ipa sile nikan lo ni ilosiwaju ati orire lenu ise bikose eniti oba nse ise ti ise tire, Olorun ti se liana ise olokuluku sile fun.(Psalm 37:23 Jeremiah 10:23) Nitorina mase lo agbara re lasan lori ise ti ko lere fun o, nitori ki ise ise re, nitorina ni (Oniwasu 9:11) fi wi bayi pe: Mo pada mo si ri labe orun pe ireije ki ise ti eniti o yara beeni ogun ki ise ti alagbara, beNI onje ki ise to ologbon, beni oro ki ise ti eni oye, be ni ojurere ki se ti ologbo-inu, sugbon igba ati ese nse si gbogbo won. Nitorina ope ni fun Oluwa ti o fun wa ni ore- ofe ati imo yui ire awa omo eniyan lati mo ise ti olukuluku eniyan ti a bi ninu osu kan. ENITI ABABI NINU OSU JANUARY:- Ise ti o dara fun iru eniyan be ni ise owo sise oja tita ise mekaniki (Mechanic and Engineerin) Ise Motor ati orisirisi ise ero, ise oselu Politican) ise abere ASIRI IRAWO EDA BY PROPHET-ADEJESU lorisirisi osu yi ni ise aso orisirisi ona ati ise aso orisi reran (Dress making) ise abere lorisirisi ona ati ise onje sis eta, tabi ise Hotel ile onje fun awon ero. Opolopo awon ti a ba bi ninu osu yi yio feran irin-ajo lilo. FEBRUARY:- Ise ti o dara ju fun iru eniyan be ni ise egbogi-iwosan Nosi (Nurse) ise dokita (Doctor) Agbejoro (Lawyer) ise orin kiko tabi ise apinta (carpenter) Awon ti a ba bi ninu osu yi a ma ni ebun opolopo pupo fun eko won. MARCH:-Gbogbo ise akowe ise omowe ló dara fun eniti a ba bi ninu osu yi ati Oga ile kiko (Architect) ise kontrakito (Contractor) ise omo-ogun (Army) ati ise isin Olorun lorisirisi ona. APRIL:- Ise ti odara ju fun iru eniyan be ni ise iwe kiko (writing )lorisirisi ona,ise Organist ati are sise kiri (Operatic stage) awon ti a ba bi ninu osu yi a ma je oloto enia nibikibi tabi ninu ise ti won bawa, nwon se ASIRI IRAWO EDA BY PROPHET-ADEJESU gbekele. MAY:- Awon ti a ba bi ninu osu yi a n ma ni opolo (Brain) nwon a si ma ni imo pupo nipa eko iwe lorisirisi, Orisirisi iseowo, ise ile-kiko, ise-ero (Building and Engineering) dara fun won. Nwon a si ma je alasodun eniyan. JUNE:-Ise ti o dara ju fun iru eniyan be ni ise Eko ijinle, ise oselu, ise alakoso opo enia ise noosi (Nurse) taabi Dokita (Doctor), Nwon a ma se orire ninu ise ni ilu ajeji, nwon a ma feran ati ma rin irin ajo, ise oja tita ati ise oluko (Teacher)dara fun won Awon ti a ba bi ninu osu yi a ma lanu enuyan loju, won a si ma feran awon omode. JULY:-Ise ti o dara ju fun iru eniyan be ni ise ero lorisirisi on (Engineering) ise ina Iletirika (Electrical works) ise owo orisirisi, ise foto (Photograher) ati oja tita ninu (shop keeper). ASIRI IRAWO EDA BY PROPHET-ADEJESU AUGUST:- Awon ti a ba bi ninu opolopo ise tin won ba dawole gegebi ebun ogbon ti Olorun fun nwon. awon ise ti o tun dara fun won julo ni ise Atuko (Sailor) tabi orisirisi ise oko oju-omi, ise oja tita lorisiris, ise onigbagbo (Auctioneer) ise agbe, ohun-osin tita, ise Oluko (Teacher), ise awonle (Surveyor) ati ise onje sise e ta. SEPTEMBER:- Ise ti o dara ju fun iru eniyan be ni ise Ijoba lorisirisi ona oja tita, ise Dokita (Doctor) Ise Nosi (Nurse ise Loya (Lawyer), ati ise Olukoni (Teacher). OCTOBER :- Omo kurin ti a ba bi ninu osu yi ko ni fe ma duro pe nibi ise kan, ki yio si bikita tabi fóju si oro owo tobe, iru iwa ni yi yio fe mu u rehin die ti ko ba yi pada, Ise ti o dara fun won ni ise Olukoni ati ise ti o ba fara mo irin-ajo lilo nigba gbogbo inu oko oju-omi, nwon ko ni fe ma teriba pelu tulasi fun enikeni, nwon a si tete ma di oga nibi ASIRI IRAWO EDA BY PROPHET-ADEJESU ise, ise ti o dara fun omobinrin won ni ise oja tita, onisowo ise akowe. NOVEMBER:- Ise ti odara ju fun eniti a ba bi ninu osu yi ise oniwasu nitoripe yio ni ebun iwasu pupo, nwon a si ma se orire ati asiki ninu ise tin won ban se awon ise ti o tun dara fun won ni Ise Noosi (Nurse) Dokita (Doctor), ise owo lorisiris, Ise iwe kiko (writing ati akojo iwe) lorisiris ona, nwon o si se asiki ati orire pupo nipa ise iwe na. DECEMBER:- Awon ti a ba bi ninu osu yi a ma wulo pupo nwon a si ma ni ebun orisirisi ise-owo, awon ise ti odara ju fun won ni ise ero(Engineering) ise Mekaniki (Mechanic) ise irohin Jounalist ati ise akowe lorisirisi ona. “ITUMO AMIN ATI APERE TI ANRETI” Oplopo ami ati apere ti awa eniyan nri láiye ASIRI IRAWO EDA BY PROPHET-ADEJESU yi ni o ni itumo, sugbo ki ise gbogbo won ni oni itumo, tabi je Pataki, awon ti oni ni itumo Pataki ni iwonyi:1. Bi atari re ba nhun o ju bi o ti ye lo; itumo re nipe iwo yio bo sipo giga kan lojo aiye re tabi laipe. 2. Bi ipenpeju oju otun ki o ri ore nipa iwo yio ri ohun ti o dun moo, tabi ki o ri ore to ti lo siidale lojo pipe, tabi ki o ta re pada wa di ore re. 3. Bi ipenpe oju osi re ba nhun o pupo, itumo re nipe iwo yio ri ohun ti ko dun moo, bi oku ore re Pataki tabi isele miran ti o buru. 4. Bi eti re ba nke gere, itumo re nip e iwo yio gbo irohin ayo kan laipe. 5. Bi eti re osi ba nke gere, itumo re re nipe iwo yio gbo irohin buburu kan laipe lati okere. ASIRI IRAWO EDA BY PROPHET-ADEJESU 6. Bi eti osi re ban kun ti o ba npariwo, itumo re enikan nsoro re lehin ni buburu. 7. Bi imure ba nhun o ju bi oti ye, itumo re nipe oro ijongbon ati ibanuje ko jinna si o, nitorina ma gbadura ki o si ma sora. 8. Bi ejika re otun bah un o, itumo re nipe ohun kan yio bo sodo re, ti yio si je ohun ayo. 9. Bi ejika re osi ba nhun o,itumo re nipe nipe ohun kan yio bo sodo re ti se ohun ijongbo, nitorina sora . 10. Bi atelewo re otun ba hun o, iwo yio ri owo kan gba laipe. 11. Bi atelewo osi ba nhun o, iwo yio na owo kan laipe ti ise inawo ti ko dun mo o. 12. Bi orunkun re otun ba nhuno, itumo re nipe iwo yio bo si ipo titun miran ti o yato si eyiti iwo ti wa tele, igba yio yi pada sir ere fun o, ati pe iwo yio je olusin Olorun ju bi o ASIRI IRAWO EDA BY PROPHET-ADEJESU ti je tele lo, emi Olorun yio ma gbile lokan re. 13. Bi ikun (Inu) re ba nhun o, itumo re nipe pe, o pe o si ibi ase onje kan laipe. ITUMO AMI DUDU ARAENIYAN 1. Bi ami dudu ribiribi ti o han dada ba wa ni iwaju ori eniyan lapa otun o fi han pe eni na yio di oloro lojiji ni igbesi aiye re, okiki re yio si kan. 2. Bi ami dudu ba wa loke ipenpeju oju otun, o fihan pe eni na yio tete gbeyawo, eni ti yio si fe yio si je olori're eniyan ati alasiki. 3. Bi ami dudu ba wa ni ereke apa otun, tabi ti osi, o fihan pe eni na ki yio je oloro ju bi o ti ye beni ki yo si je talaka ju bi o ti ye lo. 4. Bi ami dudu ba wa wa lori imu, o fihan pe eni na yio ma se ori're ninu opolopo idawole re. 5. Bi ami dudu ba wa lara ete ti oke tabi ti isale, o fihan pe eni na yio fe ma se nkan ti o ASIRI IRAWO EDA BY PROPHET-ADEJESU lewu, yio si je eniti o ni ife rere sieniyan, eyi yio si ma fun u ni isegun lona re. 6. Bi amin dudu ba wa ni agbon eniyan o fihan pe eni na yio je alasiki eniyan ati eni giga. 7. Bi ami dudu ba wa ni ona ofun lode, o fihan pe, o di igbati eni na ba se igbeyawo ki asiki re to ma posii. 8. Bi ami dudu ba wa lara omu apa otun, o fihan pe iresile yio de ba eni na lojiji ni sa kan ni igbesi aiye re, omobirin ni yio si poju ninu awon omo re. 9. Bi ami dudu ba wa lara omu apa osi, o fihan pe eni na yio ma se ori're ati asiki ninu idawole re, yio si je eniti o ni ife rere si eniyan, omokurin ni yio si je eniti o ni ife ree si eniyan, omokurin ni yio poju ninu awon omo re. 10. Bi ami dudu ba wa ni okan aiya eniyan, ofihan pe Alafia ati ori re yio po fun eni na. ASIRI IRAWO EDA BY PROPHET-ADEJESU 11. Bi ami dudu bawa lara itan ese otun eniyan, o fihan pe ole ati alajeki ni eni na. 12. Bi ami dudu ba wa lara itan ese osi ofihan pe eni na yio di oloro nikehin, yio si se ori're nipa igbeyawo. 13. Bi ami dudu ba wa lara itan ese osi, ofihan pe eni na yio se wahala die ni igbesi aiye re, yio si je eniti awon enia ko kasi. 14. Bi ami dudu ba wa ni orokun ese otun, o fihan pe eni na yio se ori're nipa igbeyawo, sugbon yio ba isoro die pade ni igbesi aiye re. 15. Bi ami dudu bawa ni orokun ese osi, ofihan pe eni na yio je oni wadu-wadu ati alainironu eniyan sugbon ni ikehin aiye re, yio di eniyan pele ati oloto oniwa-rere. AKIYESI:- Iru nkan wonyi je apa kan ninu ohun ti eniyan npe ni kadara (Akosile ti Olorun ko fun olukuluku eda) osi ye ki o dawa loju pe, iru nkan be wa fun olukuluku eniyan, eyi ti Olorun ti se liana ti Olokuluku ASIRI IRAWO EDA BY PROPHET-ADEJESU sile fun u ti enikeni ko si le yi pada (Owe20:24), Orin Da. 37:23 ati Jer. 10:23 IWE ASIRI IRAWO EDA VOLUME [1] COMPLETE BY PROHET-ADEJESU THE GRATEST ADEPTUS 09033632885 WATCHOUT FOR PART [2] ASIRI IRAWO EDA BY PROPHET-ADEJESU