AKIESI PATAKI Gbogbo iwe ti ase jade loni aworan Prof Awo Irawo ninu titori idi eyi sora lati ra aiye deru iwe Tel : 00229 62344788 0023408098692587 roufai.mohamed@facebook.com IRAWO RE PELU ISE ASELA RE ORO ISIWAJU Ki oluwa maje ki ase ise onise ; Eni se ise onise loman pariwo kiri ile adahunse pe aiye nse ohun ; Eni mu ise re pon tosi yori si rere lomo araiye ma as ope omu lukudi, ose ogun awure sibi oja re ati bebelo, ile aye konira rara, eda inure ti nwon nse ise onise ni zon npariwo enu pe ita le, kosi owo lode ati bebelo : eni irawo re se ise jagunjagun bi aries ti nlo ta eja enia o timo pe osina Eyin oluka iwe yie e fi ara bale ka iwe yi tan sn ki oronu re wo daradara ki oranti olorin tio o ko bayi pe \ ki aiye mama pa kadara wa da, ara nbe ta fe da eyi tu ;osi pe onan ise asela ohun lohun wa yi sugbon awon ti won se ise onise ti won jowu ohun, ki won ma le ranti ati gbe ti ohun se, Gbogbo wa lamo pe awon ti won se ise onise lati aro di ale, pupo ninu won ti won o ba ni emi olohun ninu ti won baranti awon ti won jo betre ti won ti ni lari, biri tiwon ba yi pada won aparada di Asa ti o ngbe o omo adie je ; Iwo ti osi wa ni idi ise boya eni oda, ola ada, ron piwada, masin ori olori ku, mu ona ise asela re pon oluwa yio mu e yori e si rere ki otodi ojo ale ; Iwo ti oba si ti gbo ma pada di asa, toju iwe yi fun omo ti oba bi yio wulo fun, Ranti npe iran meta kole to si po dandan ari eyi ti o jana ; Ranti Iran tie ti omadi oloro lehin ola dandan Asa Egbe re toba ku lehin loma gbe iran re ti oloro mi ; Iwo ti osi mo ijo ti abie ti o kosi fe se ise onise, jowo pe mi sori number mi ORO NIPA IRAWO ATI OHUN TI O BAA IRAWO OLUKALUKU MUN LAYE Opo Obi loti da igbese aiye omo re ru nipa pe dandan ise bayi bayi ni o gbodo ko, Olukuluku eda ni Olohun ti fun ni ise ti yio maa se laye, sugbon latari agidi ti awa omo Eda Adamo ni koje ki a ni ifura. Oro Olohun ko le ye omungo Eda sugbon Ologbon eni ni nye, Opo ti o yeki o lo se ise Briclayer sugbon alani akiyesi ko je ki o tete yan ise ori re layo, Eda ti o baa je omi laye ti o baa nse ise ina kole ni aluyo laye, eda to si je ina ti o nlo nse ise omi kole ni ilosiwaju laye. Imo nipa Irawo se koko laye awa omo eda, eleyi a jeki eda mo iru igbese aiye ti o le gbe, ohun ti oye ki a maa se ati ohun ti koye ki ase. Eda ti OIohun da lati ara omi ti o waa nlo se ise ni ile ise Bread, ki se epe raara kole ni aluyo laye. Ti abati bi omo Ejeki a gbiyanju ki a to awon to ni imo nipa Izab wiwo ki won se alaye lori Iru irawo ti omo naa gbe waa si aiye, iru ise ti ole se. Esu koni da irin Ajo gbogbo waa ru mo wa lowo laye. Amin IRAWO RE PELU ISE ASELA RE IGBEYAWO Igbeyawo kiise ohun ti ole wole ki osare jade, idi niyi ti yoruba fima nso ni oro wipe oloko meji koni duro lori eyokan oro yi wa fun awon ti oba sina fe oko oloko papa awon ojise olorun alfa ati adahunse ma ntan opolopo eniyan je won aba won ye ise wo won a ni awon ri ibujoko wa nibe nitori awon ri omo larin won oto ni ki irawo oko ati iyawo ba papo oto ni pelu ti irawo oko ati iyawo ba funwon ose wo. Iwo ti oba si ti lofe okoloko ti omo bati wa larin igbeyawo yin mase fi oko e sile sugbon toju Iwe yi fun awon omo re nitorie ojo iwaju ki omobatun ri biti tire. Mo loba enikeni mo rara, wo ojo ibi ti iyawo ati ti oko ki ofimo boya oto kiwon fe ara tabi ko to. Ni naye ojosi, ama nwadi idile ti omo wa ti fe loko tabi ni aya sugbon ni ode oni kosi iru e mo, ife ni won nlo fi ni oko tabi aya. Omo ti oba fi ara bale yio gbadun igbeyawo re de ojo ale. Eyiti koba fi ara bale ni oro olopko meji koni duro lori eyokan. Ti iru awon wonyi ko ba rora se won yoo di oloko meta koni duro lori meji ati papa oloko merin koni duro lori meta, awon miran atun ni irun eni bayi kolori oko laimo wipe gbogbo eda ti oba konju ni oko laise iwadi lori irawo won boya oba ra mu tabi koba ara won mu yoo kanju jade. Mase gbagbe wipe oja meji ni awa na ni aye, oja akini mofe ra motor, aso, bata ati bebe lo, wa mu ojo losi oja lati eyeti odara ; sugbon oja keji mofe fe oko mofe fe iyawo odi dandan ki o mu ori lo, or iwa koni tiwa lofe oko oloko tabi aya alaya amin fun alaye ni eku rere tabi oni ikose lori igbeyawo re tabi igbeyawo re koso eso rara etc….. yowo gbiyan ju lati ri Prof Awo Irawo IRAWO RE PELU ISE ASELA RE ORUKO AWON IRAWO Aries belier ; Taurus tauraux ; Cancer cancer; Germini germaux ; Leo lion; Virgo vierge; Libra balance; Scorpio scopion ; Sagitaire sagitaire ; Capricorn capricorne ; Aquarus verseaux ; Pisces poisson ; IRAWO INA Aries ; Leo ; Sagitaire IRAWO IYEPE Taurus ; Virgo ; Capricorn IRAWO ATEGUN Germini ; Libra ; Aquarus IRAWO OMI Pisces ; Cancer ; Scorp Symbole Signe astrologique Date ♈ Bélier Aries 22 mars au 22 avril Inan ♉ Taureau Taurus 23 avril au 22 mai Yerupe ♊ Gémeaux Germini 23 mai au 22 juin Afefe ♋ Cancer Cancer 23 juin au 23 juillet Omi ♌ Lion Leo 24 juillet au 23 août Inan ♍ Vierge Virgo 24 août au 22 sept Yerupe ♎ Balance Libra 23 sept au 22 octobre Afefe ♏ Scorpion Scorpion 23 octobre au 22 nov Omi ♐ Sagittaire Sagitarus 23 novembre au 22 déc Inan ♑ Capricorne Capricorn 23 décembre au 20 jan Yerupe ♒ Verseau Aquarus 21 janvier au 20 février Afefe ♓ Poissons Pices 21 février au 21 mars Omi Élément IRAWO RE PELU ISE ASELA RE AJOGBE AWON IRAWO KANKAN LOTOTO ATI LAPAPO FUN GBOGBO AWON TI WON SE DARA PO MOWA ATI AWON TI WON BERE LORI AJOGBE PO 1 ) Ajogbe Po Adamo Omi ati Omi Ire Omo Iya mi ninu esin islam mo fe ki e mo wipe awon Irawo yi ni O re won si ni ota awon Irawo Omi ati Omi lee fe ara won tabi ki won mura won ni Ore won si le jo da Ise papo. Pelu opolopo suru 2) Ajogbe Po Adamo Omi ati Yerupe Bakanna ni Omi le fe yerupe, won si le mura won ni Ore won sile jo da Ise po Bi o ti leje pe yerupe ni Ise ajose yen ma gbe. 3) Ajogbe Po Adamo Omi ati Ina Lotito ni opo ninu awon Onimimo nipa Irawo ko fi owo si ajogbe Irawo Omi ati Ina, nitori Omi yoo pada Pa Ina, Sugbon won le jo da Ise po won sile fera won ti won ko ba jo gbe papo lo dara ju nitori Ija. Koda won le ma ba ara won Sore, sugbon won yoo pada tuka pelu Ija tabi lori Ireje ti yio ma sele larin ara won pelu aifinu han ara eni tan. 4 ) Ajogbe Po Adamo Omi ati Afefe Awon Onimimo nipa Ijinle Irawo tako Ajogbe Irawo Omi ati Afefe, nitori wahala ati idamu ti afefe saaba ma nkoba Omi, sugbon won le fera won gegebi toko taya won si le jo sore tabi ki won jo da Ise po bio ti je pe won yo tete ma ri asise ara won ki si nii si Igbadun fun Afefe pupo nitori Afefe yoo ma fe si Omi Omi yo si ma tan kakiri eyi tumo si wipe Omi ni ajogbe won yo gbe pupo. 5) Ajogbe Po Adamo Yerupe ati Yerupe Ajogbe awon Irawo yerupe ati yerupe dara pupo oore si ma nbe nibe ajogbe won Ti o ba je wipe yerupe ati yerupe ba fe ara won tabi won mu ra won ni Ore tabi won jo da Ise po odara pupo won ki si ri Inira tabi Ija rara Afi ti eniyan kan ba wo won larin ni o le fa Ituka. Be sini Adamo yerupe ati Omi naa. IRAWO RE PELU ISE ASELA RE 6 ) Ajogbe Po Adamo Yerupe ati Ina Opolopo ninu awon Onimimo Ijinle ninu Irawo ni won ko fi owo si ajogbe yerupe ati Ina, nitori inira ati wahala ti ina yo ma fun yerupe ti ko si le ke sita sugbon won le fe ara won gegebi toko taya won si le mura won ni Ore tabi ki won jo da Ise po sugbon Ina yo pada re yerupe je nitori yerupe koni fe Ija be sini ko ni je ki o ma soro lasiko ti o baye ki o soro yoda ni awon yerupe fi ma nko nira ba ara won ni odo awon Irawo Ina gbogbo ise ti yerupe ba se Ina ni yio fi sin won yo pada tuka ni ayafi ti Adamo yerupe ba fi Ori ro inira yan loku. 7 ) Ajogbe Po Adamo Yerupe ati Afefe Awon Ojogbon ninu Imo Adamo ko fi ara mo Ajogbe Irawo yerupe ati afefe nitori wahala ati fitina ti Adamo Afefe ma nko ba Irawo yerupe sugbon won le fera won gegebi toko taya ti won ba fe ki Ajogbe Ife naa pe dada won le ma gbe papo ninu ile kunna nitori ti o ba je Okunrin ni Irawo Afefe koni ma fi Ife han si Adamo yerupe gbogbo owun ti Irawo yerupe ba se ni ko ni mo se loju Irawo Afefe yo tete ma ka ese si lese, won le mura won ni Ore won si le da owo papo sugbon Afefe yo ma re yerupe je 8) Ajogbe Po Adamo Ina ati Ina Ajogbe Irawo Ina ati Ina ni o dara ju lati fe ara won tabi ki won mura won ni Ore, won si le jo da owo papo Oore nla nla si ma njade ninu Idawole won papo won fitina tabi wahala kii si sele larin ara won Ayafi ti awon iyawo won ba tuwonka loku ti o baje toko taya ni awon molebi ni won ma nda arin won ru tabi Ore Bakanna… IRAWO RE PELU ISE ASELA RE AWON EGBO IGI TI O DARA FUN IRAWO RE 1. IRAWO AFEFE Je eniti yio maa se Adua daadaa, ki osi maa tan Turari pupo ni igbati o baa nse Adua lowo, Maa lo Turari Adua dada ni gbogbo igba, Aseje, Ose, ati Etu ntete maa nsise lara iru irawo yii nidiwon ti won baa nti nse adua ki won to lo 2. IRAWO OMI Ki won je iru Eda ti o nlo unkan ti won fi omi pipe, gegebi Hantu mumu, Obe Aseje tabi ki won maa we ose dudu. Ebu Jijo ki sise lara won, bi won baa fi one million se ebu fun iru won kole ri one naira ni ibe. 3. IRAWO INA Irawo ina gbodo sora fun wiwe ose ni gbogbo igba, Ohun ti o dara fun iru irawo yii naa ni Ki won maa lo Ebu ti a jo.. Ebu ni o nsaba maa sise pupo fun won ju gbogbo ogun miran lo, Awon Ogun miran naa maa nsise fun won sugbon ko dabi ki won lo Etu 4. IRAWO IYEPE Irawo yii gbodo maa se Sara Daadaa, ki won maa fon awon unkan jije si ile fun awon eda ti won nse aiye iyepe, Ose Dudu ati Aseje dara pupo fun won AKIYESI PATAKI Opo igba ni awa omo eda nsun gbagbe, opo ninu eda ni koni akiyesi, opo lo ti lo se ayewo si oro aiye re ti obaa de ibi kan bi won ko ba so wipe awon agba lo nda lamun won asope iya re ni o waa ni idi oro re, igbamiran won a ni egun idile, ohun ti awa omo eda nfi owo ara waa faa gan ngba miran gan ju ki awon apapo agba ma da enia lamun lo. Ojo kokan ninu osu loni ohun ti o nba enikokan wa rin, Irawo ati Ojo ibi maa nda opo eda lamun, ,, opo igba loti lo ogun dudu sibe sibe pabo lo nja si, boya eleda re ko lo ni ilana unkan be sibe sibe o ko agidi bori oni dandan iwo naa fe se ogun osole! 1) Irawo Omi, Ewe ki je lara iwo omi, ogun asasi ota ki si saba ran won, Je enikan ti yio maa saba lo Hantu, tabi ki o maa se Adua si omi, Ebu lilo ki je lara won, bi won ba fi Millions se Ebu fun won ko le sise, Ose si nma nsise die die lara ju Ebu lo IRAWO RE PELU ISE ASELA RE 2) Irawo Ina. Ha! Irawo yii gbodo je enikan ti o nso ara re kuro lori wiwe ose ni gbogbo igba, Bi ose wiwe ba po lapoju o da gegebi eni npa ogo ati imole ara re ni, Ebu a maa sise daadaa lara won ju ose lo 3. 3) Irawo Afefe... Awon irawo yi gbodo je enia ti ntera mo adua sise lopo lopo, bi won se ni agbara to be naa ni won yaa ole (lazy) to, ogun asi maa tete je lara won, besi ni asasi ntete maa nmun won, won gbodo munra gidi gidi, won ki fe ki won se aseyege eko, enia nla ni won. 4) Irawo Iyepe, Awon irawo yii maa nje oni suru, won ki tete binu, won gba iwosi sugbon bi won ba binu tan ibinu won ko dara raa, won ki si fe gbo imoran eda miran yato si ti won, inakuna asi maa ba won ja pupo, bi iru irawo yii baa tete munra si isori lati ibere pepe aiye won, won ama bori Awon isoro bi ki owo maa daa lowo won. IRAWO RE PELU ISE ASELA RE Aries Belier March 22 – avril 22 Oruko Irawo akoko yii ni ‘’Omo ti a ba bi ni March 22 titi de April 22 yoo je omo ti yoo maa huwa aigboran. Nigba miiran, iwa agidi won le maa fi iya je, tabi se won ni rere. Aisiki ko po fun won to bee, ti won ba n sise labe aniyan afi ki won je oga ise ara won. Ki won da ise ara won sile. Won ko gbodo ba eniyan da ise po, ewu wa fun won ti won ba se bee. A bi Aries ni Irawo kan ti a n pe ni Mars ti ode orun, ti n joba ile kinni ninu kadara eda. Eyi yoo fun won ni igboya, agbara ati iwa okikanju, won si le je eniyan ti o ni iwa agidi ati orikunkun nigba ti won ba n fe ohun kohun. Suuru kii se ebun won, o si soro fun won lati ni ore otito ti yoo wa pelu won fun ojo pipe nitori pe won je alagidi ati eda ti o feran iwa asahan, enu-didun ati karimi. Irawo won yii lo n joba agbara ati imusasa tabi idasasa, eyi lo si fun won ni abuda ara gbigbona ati owu jije tabi fifi itara pupo se ohun gbogbo. Irawo won si kun fun ogun jija ati iwa lile bi ti jagunjagun. Iwa won yii nii je ki gbogbo nkan ti won ba dawole maa yori sir ere, oun naa ni kii je ki won gbe ibi kan nitori ainisuru to won. Olukuluku eniyan lo ni iwa ati abuda rere ni apa kan ati eyi ti ko dara ni apa keji. Ohun kohun yowu ti oluwa re le je, ko si eniyan kan ti o je maleeka patapata, bee si ni ko si eda kan ti o kuku je omo satani san-an, ti ko si ni rere kan ninu igbesi aye re ti i se. Ina ni a fi se eda won, eyi yoo si fun won ni ookun ati agbara itagiri, ti won yoo fi je onigboya eniyan ati eni ti o yara pupo. Won yoo je eniyan ti ko beru lati so otito bi o tile je pe eyi le so won di ota opolopo eniyan. Won yoo ni aya bi ti kinnihun, won ko ni fe je omo ehin ninu ohun kohun bi ko se asiwaju. Lati igba ewe won ni iwa odaju ati igboya yoo ti wa fun won, a si kiyesi I npe gbogbo omo ti a ba bi labe ase irawo yii n fe amojuto gidigidi lati igba ewe won wa, ki iwa orikunkun won ma ba won dagba ki won ma baa di omokomo. Won o je eniyan ti o ni aapon ati akikanju pupo ni igbesi aye won. Won yoo si mo eto ohun gbogbo ni sise lona ti o to laarin ore, alabase, alabagbe ati alabarin won. Awon ni yoo saaba fe je olori ati asiwaju. O si tun seese ki won maa gbidanwo lati fi agidi se nkan. Nigba miiran aini suuru to won ni o maa n je ki won so awon nkan ti elomiran I ba fun won nu, nipa pe kekere ko to won afi bi won fi won ba gba nla. Won je eniyan to lawo to bee ge ti won fi le maa gbo bukata awon ore tabi ibatan won. Ibukun, orire, owo nini ati idunnu wa fun won ni igbesi aye won ti won ba le ni suuru. Mo ro won ki won maa toju owo nitori ojo ale won, ki won ma baa IRAWO RE PELU ISE ASELA RE kabamo. Won yoo maa wo aso daradara, won a si feran nnkan oso lati maa lo fun ara ati omo won pelu. Won feran lati maa tan elomiiran je, sugbon ti won ba si ri aisedeede lati odo eni keni, ki won ni suuru, ayo ni yoo jasi fun won nikehin. IKILO: E maa sora fun iwa akoba lenu ise, ki e ma ba eni keni ledi apo po se ohun to lodi si ofin, ki e maa ba kabamo. E ma se kegbekegbe ni ibi ise, e sora ki e ma gba ija onija ki eleyi ma baa yori si ota. E ma se wahala aseju lori ise ti ko nilaari, e maa se suuru fun gbogbo nnkan ki e si sora lati ma wo aago alaago sise. Won je eniyan ti o ma an tete nilaari ni igbesi aye won sugbon ki won ma se je ki ola bo won loju lati ma le se ife Olorun. Paripari re ni pe ki won sora fun iwa buburu lati hu si eni keni. E je iru eniyan ti ko gbodo fi aye sile fun igaara tabi iwa emi ni mo to yii, bi e ba se bee asilo agbara ti Olorun fun yin ni, o si le yori si isubu tabi iparun ojiji. Nigba miiran emi itara ati aapon ti e ni yoo maa ti yin, o si le so yin di alailero tabi alaini suuru. Nipa aironu jinle ki a to se nkankan tabi aifi suuru se e, eyi le koba eniyan ki onitohun si fi owo ara re fa isoro tabi yanpon-yanrin ba ara re. E sora nipa fifi agidi tabi tipa-tikuuku je asiwaju, e ma se je ki inufufu bo yin loju, ki e si ti ipa bee huwa tabi soro ti ko ni tan nile. E ma se je ki aifarabale mu yin huwa tabi soro ko-a-tan, ni igba pupo, o le je iwa enu fifun tabi gbigbe ara eni ga ju bi a ti to lo ni a o fi fa akoba fun ara eni. Nipa aile ko ara eni ni ija nu tabi fi asiri ara eni pamo, ko dara ki e maa fi gba bo oro ti e e ba gbo lenu eni keni se ibinu, ifarada se pataki julo. E gbiyanju lati le maa pa asiri ara yin mo ati ti awon elomiiran, iwa aleebu yin kan tun ni eyi. E ma se taku si ibi ise ti ko fun yin ni ere, ki e ma si se je ki ija onija di tiyin, e ma si se gbagbe tati fun ara yin ni isinmi. E ma se fi oro tembelu eni keni tabi yaju si eniyan e ma si se jo ara yin loju nipa agbara, e gbiyanju lati maa gba imoran. Eyin obinrin, e maa bowo fun oko yin, ki awon okunrin si maa toju iyawo won. ILERA : Aisan ti yoo maa yoju si won ni efori, otutu, oju didun, iba, ooyi, ara riro ati eje riru. ISE : Ise ti o dara fun won niwonyii : Ise ero lorisirisi ona, oselu, ina monamona (electrical work), hoteeli (hotel), owo sise ati akowe oja. Won si tun le se ojise Olurun, olopaa, onisegun (doctor), akowe labe ijoba, gbogbo ise ni o ba won lara mu sugbon iseda won ko ba eniyan da ise po, ki won sora fun inakuna. IRAWO RE PELU ISE ASELA RE IGBEYAWO: Iyawo tabi oko ti o ba won mu niwonyii: Leo, Aries ati Sagittarius. Won si le fe ninu awon irawo miiran pelu suuru ati adura. Awo to ba oriire won mu ni awo pupa tabi eyikeyi ti o ba tan daradara. Ojo Isegun (Tuesday) ni ojo oriire won, nomba oriire won si ni 9, 18, 27 ati 54. Abela ti o dara fun won lati maa lo fun adura ni pupa resuresu (pink) pupa ti o ni awo ofeefee ninu (orange) ati pupa foo (red). Awure tabi isora (Talisman) ti a pinle se fun won labe ase irawo won lo ba won mu. Iwo obinrin ti a bi labe ase irawo yii, boya e lewa ni tabi e burewa, ohun ti a kiyesi nipe ife yin a maa gbona gidigidi lokan eni ti e ba nife. O si seese ki iwo obinrin je ojowu, ko si obinrin ti kii jowu sugbon ti obinrin irawo yii yoo fere peleke kii se aimo iwa hu won bi ko se pe abuda won ni inu fufu, igbakuugba si ni won maa n binu pelu, sugbon mo ro won lati maa bu omi suuru mu. April 22 – may 22 Oruko Irawo akoko yii ni ‘’Tauros’’ Omo ti a ba bi lati April 22 titi de may 22 yoo je eniyan jeeje ti kii tete binu, sugbon eekan ti ibinu iru won baru soke, won kii tete gbebe. Ahun ni won nitori pe won hawo. Bi o tile je pe alaanu ni won, sibe won maa n wonkoko mo ohun ini won ju bi o ti ye lo. Iru won se ba keebe, ologbon ni won, iruwon ni ipamora, won si maa n tete faramo samooni iyowu ti o de si won. Won feran alaafia ati irepo lopolopo. Won kii si ko lati maa fi egbin mora nigba miiran tabi lati padanu ohun kan ki irepo ba le wa ni ibi kibi. Iru won je eniyan ti o n duro tinpinnu tabi ileri won. Eyi si le je pelu ori kunkun ati aife se ayipada okan nigba miiran. Irawo ti n joba igbesi aye won yii naa ni n joba oro ife, eyi yoo fun won ni abuda ati iriri ti o ni ise pupo pelu awon abinrin ati okunrin. Irawo wonyii je eyi ti o fun won ni emi iforiti ati opolopo suuru. Won je eniyan ti won feran lati maa fi eto ti o gbamuse se ohun gbogbo, won yoo feran ohun ti o lewa, oso sise ati nnkan osin. Ti won ko ba sora, obinrin ti kii gbele oko ni won o fe sile, ni warasesa ni won yoo salo. Won o ni owo sugbon inukuna ni won o maa na an. IRAWO RE PELU ISE ASELA RE Mo ro won ki won sora fun inakuna nitori bi oni ti ri, ola le ma ri bee ko si si eni ti o mo eyin ola. Ibinu kii pe tan ninu won, bi o tile je pe won ni orikunkun ti o le fa akoba ba won. Obinrin Taurus maa n feran oko won pupo, amo sa, won feran ounje pelu. Won maa n ran awan obi won ati gbogbo eniyan lowo, won lawo si eni ti Olurun ba ran won si sugbon obinrin won maa n bimo ju okunrin lo. Tokunrin tobinrin awon irawo yii ma n lowo. Bi wahala ba wa fun won lowuro, asale won nilati dun yungba-yungba ni, ki won ni suuru, elemi gigun si ni won pelu. Olorun da awon irawo yii yato nitori pe bi eniyan sa oogun si won, kii ran won rara. Won si korira opuro ati alajaigbiba eniyan. Bi won ti je ologbon ati alaanu to ni won je eniyan Olorun ti won si ni arojinle lati fi okan te tabi gbekele nnkankan nitori ojo ale. Abajo ti owe tabi asayan oro awon baba nla wa ti o wi pe ‘’agbekele ko pa ni lebi’’ fe se iwo mo won lara nbi o ti kan won gbon-gbonon-gbon to. Olooto eniyan ati ore ti o se gbekele ni won je, won si ni ife gbogbo eniyan. Won maa n ni oro pupo sugbon won feran lati maa wo owo mo ohun ini won ju bi o ti ye lo, koda, won le toju nnkan won pupo ju. IKILO : E mu suuru daradara ki e si wadi finnifinni ki e to gbe iyawo. E ma se na inakuna, bee ni ki e ma se ilara omonikeji, e je ki ohun ti e ba ni te yin lohun. E ma se wo aago alaago sise, ki e ma si se maa se aabo ise e sora fun oti mimu. Bi eniyan kan gbe yin ga, esora nitori pe ota yin n be laarin won. E ma se mu oti lile rara, bee ni ki e ma se ta oti nitori adanu. E sora lati ma se gba ona eburu wa owo nitori ona iparun ni eyi yoo yorisi fun yin. Bi suuru yin ti po to, bee naa si ni orikunkun to nigba ti e ba n binu. O seese ki e je bajumo eniyan sugbon boya iwa imo-tara-eni-nikan diedie ko le sai ma si. E je oninuure ni tooto sugbon o dabi pe ife ohun ti aye po ju lokan yin. E je eniyan ti yoo maa ni ife si baba ju iya lo, sugbon sa, e ma se maa ya nnkan lo lowo ore tabi eni keni. ILERA : Aisan ara bi ofun didun, ara riro, eje riru, ori fifo ati inu rirun po fun awon irawo yii. E sora gidigidi nipa ounje jije lode, ki o ma je pe ibe ni won yoo ti fi majele sinu ounje fun yin ti yoo si se iku pa yin tabi ki e ri aisan nibe. Nipa ti obinrin, aisan ara ti o je mo ti ibimo le maa yo won lenu, sugbon o seese ki yipada maa wa fun won ni odun kefa-kefa ni gbesi aye won. ISE : Ise ti o dara fun won ni oja tita sugbon to dara ki won ba eniyan da owo po Orisirisi ise owo ni o dara fun won Ise ile kiko (bricklaying), agbe, irohin ati IRAWO RE PELU ISE ASELA RE ounje siseta pelu, awon oti eleridodo (minerals) ni tita. Kadara won ko ba ise tete ati oti tita mu. Ise ti o pa won lokan po situn dara fun won pelu. IGBEYAWO: Irawo ti o ba won lara mu ni Taurus, Virgo, Capricon tabi Scorpion. Won le fe ninu awon irawo miiran pelu suuru ati opolopo adura. Maleeka won ni ile. Ojo ti o dara fun oriire won ni ojo Isegun ati Eti (Tuesdays ads Fridays). Awon awure tabi isora (Talisman) ti o si dara fun won ni awon ohun ti a ba se ni akanse labe ase irawo won tabi gege bi ohun ti e ba n fe. Awon Nomba oriire won ni 6, 15, 21. Awo ti o ba won lara mu ni olomi bulu ati wura (blue and old gold) GEMINI GERMAUX MAY 23 – JUNE 22 Oruko Irawo yii ni ‘’Gemini’’ omo ti a ba lati May 23 titi de June 22 yoo je eni ti yoo maa fi igbona okan gba nkan mora sugbon ko ni pe ki nkan naa to su u, yoo si je eni ti ko ni maa ni ilara. Ire ayo wa fun un, yoo si ni aapon ati agbara lati se ohun ti inure ba dun si. Awon irawo yii yoo je’a-ri-yawo-koiyale’, won kii si fe gbo alaye afi tiwon saa. Alaanu ni won, won si lawo pelu. Oniwa rere ni won, won lemi aseyori ise sugbon ologbon ewe ni won. Ogooro won lo feran awon obi won, won si laanu won pelu. Ota maa npo fun won lati maa jowu won. Mo ro won ki won sora lati maa fi inu han ore, ki o ma baa je ota ti n farahan bi ore ni won n fi inu han. Won feran lati maa jiyan pupo nitori pe ogbon ti Olorun fun won po, ogbon ori won nikan ni o pe julo loju ara won. Pupo ninu won je eniyan ti o maa n mo iwe, ti on ba ran won lowo lati ka a. ko si ibi ti won ko le ka iwe de, pelu ogbon si ni won maa n se gbogbo nnkan won. Won je eniyan ti o jafafa ti o si yara pupo sugbon ti won le soro ju Ogbon ati oye won po to bee ge ti won fi maa n fura si nnkan ijinle tabi ti o farasin si kolofin ju bi awon irawo yoku ti le mo lo. Irawo ti o si n joba won ni Mercury. Won je eniyan ti o maa n ko irin meji bona leekan soso. Won si feran nnkan mejimeji lati maa se ati pe ise kan soso kii wu won afi ki won se nnkan IRAWO RE PELU ISE ASELA RE won ni mejimeji. Nipa eleyii, won le bi omo mejimeji ni igbesi aye won pelu. Awon irawo wonyii je eniyan ti won feran iwe kika, ti won si mowe lopolopo. Sugbon won je eniyan ti kii fi ara bale ni igbesi aye won,won je eniyan ti maa nro ti elomiran mo tiwon ni igba iponju, won maa nran eniyan lowo, won kii si I fe fi eniyansile ninu wahala tabi isero won. Irin-ajo won ninu aye ko mu iniran wa fun won pupo nitori pe lona kinni, won je eniyan ti o tete n ba igba yi si ibi kibi ti o ba yi, si ati wi pe a fun won ni ebun iyebije kan. Okan ninu ebun abuda won nipe won maa n dabi omode bi won ba to omo aadota odun (50 ans), won maa n dabi omo ogun odun ni. Iri oju won ku fi ojo ori won han, aile ni okan fi okan sona kan atille teramo ohun kan ti won dawole je nnkan ti o buru jahi ninu iwa won. Won je eda kan ti o maa ndaamu okan ara won pupo, eyi si maa n yori si aisinmi okan, o si le mu wonse ayipada ile, ise, ibujoko ati awon nnkan miiran. Aini ifarabale kii je ki won le joko si idi ise kan, n se ni won yoo mu omiiran pelu tabi ki won maa fi nkan wewewe miiran se ipawoda tabi inaju pelu re. Won je eniyan ti won feran lati maa wadi nnkan ni igbesi aye won ju bi o ti won ti ye lo. Nipa ofintoto, yii, o le fa ikorira fun won tabi iota. Eyi ti o buru juto ninu iwa won ni aile pa asiri ara won mo ati ki won se iwadi gbogbo oro finnifinni lenu eniyan, bi won ba si ti gbo asiri kan, inira gidi ni fun won lati pamo, afi ki won yara maa tan an kaakiri yala iro ni tabi otito. Mo ro won lati sora ki ogbon agbonju ma koba won nigba miiran, ki won si sora fun iwa agabagebe, iyori si eyi yoo buru pupopupo. IKILO : Iwo omoge Gemini, sora pelu iwadi ofintoto, nipa gbogbo irinsi olufe re, e ko ni pe maa ja nipa sise eleyii. Iwo adelebo Gemini, fi idi mo ile okore, ma se maa yo fofo jade nigba gbogbo. Ikilo kan naa yii ti o wa fun obinrin Gemini oun naa lo wa fun okunrin won. Owu jije lona ti o ga ati ife lati saa mo gbogbo idi abajo saa, lo n fa nnkan wonyii sehin. Ko si le je ki inu didun wa ninu ile. Gbogbo igbesi aye won maa n kun fun wahala ati ibanuje miiran sugbon gbogbo re ni Oluwa yoo so di petele. Bi awon ota n daamu yin, Oluwa ni ki e maa gbadura si, maa se adura ni gbogbo igba, e ma si se dake adura nigba gbogbo, sora, e ma lo si ile babalawo nitori kadara re ko fe nkan dudu, e sora fun eleyii. Adura ni oro yin gba. ILERA : Aisan ti yoo fe maa se won ni lakuregbe, ara riro, otutu, ehin didun, inu rirun, ju gbogbo re lo ki won sora nitori ibu sisu ati ipalara, eyi yoo le mu ailera wa fun won. IRAWO RE PELU ISE ASELA RE ISE : Ise ti o dara fun won lati maa se niwonyii : Ise Olukoni, Noosi tabi Dokita, Oselu, Akowe nibi ise ijoba, owo ati ise to je mo irinajo lilo. IGBEYAWO : Awon irawo ti o ba won muniyii: Gemini, Leo, Libra ati Aquarius, pelu adura ati suuru, won le fe irawo miiran. Maleeka afefe ni Olurun fi se eda won, ojo oriire won ni ojo Abameta (satuday) ati ojeru Wednesday). Awo ti o ba won lara nmu ni pupa roro (red) ati olomi bulu (bleue) Nomba oriire won ni wonyii 5, 14, 23 ati 42. E sora pelu iwa afojudi inu fufu ati iwa ipanule to le maa mu nki nawon eniyan pokiki eni tabi yera fun won paapaa julo, ki e sora lati se eniyan ti ko ye ki e se, e le huwa buburu si elomiran ki won ma tile beere lowo yin, sugbon eru ese nla ni e di le ara yin lori, nipa bee, e ranti ojo ola ati atubotan yin. CANCER CANCER JUNE 23- JULY 23 Oruko irawo akoko yii ni ’’Cancer’’ omo ti a ba bi lati June 23 titi de July 23 yoo je obododo, omo ti a gbodo mojuto daradara lati igba ewe re. Ki a to o si ona rere ki o le wulo ni igbesi aye re re. Awon irawo yii yoo je eni ti opolopo eniyan yoo feran ti won yoo si maa tele ti ko ba fi iwa le won sa. Won yoo feran orin ati pe yoo je alaisiki eniyan. Won ni opolo pipe fun iwe nuka, won maa n mo iwe sugbon ere maa npoju fun won ti won ko ba ri eni mojuto won. Won yoo je olofofo eda ati alayojuran sugbon sa, won je alannu eda. Gege bi oga (alagemo) n se, ni won o maa saaba gba awo awon elomiiran wo, ti won o si maa gbiyanju lati se e bi tiwon. Ihuwasi yii je eyi ti o ran ni lowo pupo, paapaa julo, bi awon eniyan ti n ba keegbe ba je eni Olorun ati ologbon eda, won o je eniyan ti o sora re pupo, ko si ni ni iwa afojudi si eni keni Bakan naa, won korira iyipada ati aisimi sibi nigba gbogbo. Eyi ti agbara won ba ka ni won yoo se fun eni ti won ba feran lowo. Won feran imototo nibi kibi ti won ba wa, won maa nsaaba je oga ile ise nla, won si je olusi na sugbon won je eni kii pe binu, kii si pe ki o to tan ninu won. Won feran awon ebi won, won si ni ese lati maa wa awon ebi. Won feran oro siso, funra won ni oro inu won a si ma dun sugbon nigba ti o ba di ale, inu won maa n baje fun ironu. IRAWO RE PELU ISE ASELA RE Ni odun yowu ti a bi won labe irawo naa, Irawo ti o n joba labe ase re ni osupa (Moon). Awon obinrin won maa n ni ewa ju okunrin won lo, won si maa ni ife iya won pupo, won kii tete gbeyawo tabi ni oko, sugbon won feran tètè tita lati fi wa owo, won si je olopolo pipe eda. Won je eniyan kan ti o ni omi aanu loju pupo, olopolo ninu won ti o ba daba, yoo maa je eyi ti o tona nitorie npe won maa n ri isipaya gba, ero won lori ohun ti ko ti ri tabi ti ko tii mo tele yoo maa bosi. Onitiju eniyan ni won yoo je, won yoo si ni ifarada ati suuru pupo sugbon won je eniyan ti o maa n tete binu ti yoo si maa ka ese si eniyan lorun, won si je olokan funfun. Ero ati iwa won yoo maa saaba yipada nigba gbogbo, yoo si dabi eni pe idide okan yato fun arojinle ni yoo maa saaba dari iwa won, yoo si je asa won lati maa huwa gege bi ero tabi eko ti won gba lati odo won elomiiran. Sugbon eyi ti o tun tako eyi ninu abuda re ni wi pe o tun fi aye sile fun aibale okan ninu re lohun-un. Gege bi ore, o je eniyan ti o ni aanu pupo, sugbon ko gbe ifeloju, bee ni fi o si korira afuhan o je eniyan ti ko roju rare lati fi gbogbo agbara re han. Itiju re paapaa ni igba miiran a maa je eyi ti o jade lati inu iwa re lati maa wa ni iwontunwonsi. Eru aye a maa ba iru won pupo sugbon sibesibe iwa emi aforiti ati ifayaran yoo fere di orikunkun fun won nigba miiran. IKILO : Ma se ilara eni keji re, ma si ro ara re pin bi idanwo ba de ba o, iwo yoo bori re laipe. Mase ko ibawi eniyan, beere fun amoran ki o to dawole ohun kan. Maa lo ogbon ologbon, ki o ma se da si oro oloro ki o ma baa di tire. Kun fun suuru nigba gbogbo ki o ma se ya eleti didi si nkan ki o ma baa fa iparun ba o. maleeka ti a fi se eda re ni Omi. ILERA : Bi ooru ba mu pupo nigba gbogbo yoo maa ko aisan iba ba won, nkan gbigbona koba won lara mu. Won gbodo maa gbe nibi ti afefe wa, aisan inu rirun, ori fifo, orikeerikee ara riro ati ehin didun ko jinna si won. ISE : Oja tita lorisirisi ona, nkan oso ile ati ti ara, tita ounje, eja, oti eleridodo (Mineral), onisegun oyinbo (doctor) ati gbogbo ise ti o ba ti omi lo tabi ti a fi omi se bi ipara oloorun didun (perfume), ikunra oniyebiye (make up), nkan itowo-to-te (paints) ati beebee lo. IGBEYAWO: Awon irawo ti o ba won lara mu ni Cancer, Pièce sati Scorpion, won le fe ninu awon irawo miiran relu suuu ati adura. IRAWO RE PELU ISE ASELA RE Ojo oriire won ni Tuesday, Nomba oriire won si ni 2, 11, 20, 29. Awo ti o ba won mu ni pupa roro ati awo eweko (red and green) Maleeka ti a fi se eda won ni omi. LEO Lion JULY 24- AUGUST 23 Awon omo ti a ba bi lati July 24 titi de August 23 yoo je olododo ati oninu-fufu eniyan, won yoo si tete man ka esun si eniyan lese. Ohun kan ti ko nilaari ni won yoo maa tori re binu nigba miiran. Sugbon oro kii pe tan ninu won. Bi o tile je pe eniyan nla ti yoo si de ipo giga ni won, sibesibe won yoo ni emi idariji, oloriire ni won, won, o si ni ore pupo pelu. Kinniun ti a fi se amin Irawo won yii naa lo si je oba awon eranke. Bakan naa ewe, Wura (Gold) ni ohun oso fun irawo won yii, oun si ni irin ti o niye lori julo, ookan (01) si tun ni nomba won, eyi tii se asiwaju gbogbo awon nomba. Won je eniyan kan ti won se pataki, ti won lagbara, ti won si je alariya. Iwa ati iseda won yoo je eyi ti o maa n tan imole si ona awon elomiiran, ti o si maa n se atokun ayo ati inu didun. Bayii naa ni won gbodo maa gbiyanju lati maa mu aye ati inu didun wa sinu ohunkohun ti won ba lowo si. Won je eniyan ti a ko ka si pataki pupo laarin awon egbe ati ogba won, igba pupo ni ogo tiwon yoo si maa bo ti awon elegbe won mole. Bi o tile je pe awon eniyan wonyii yoo ni owo ati oro pupo, sibe won yoo si maa ranti alani, ti nwon yoo jo ara won loju ; inakuna ko si jinnasi won lai ro ehin ola pe bi onii ti ri, ola le maa ri bee. Won feran ise agbara, won kii jeun lakoko, arè won si maa n le. Won yoo tete lowo nigba ewe won eyi kii je ki awon irawo yii toju owo naa, sugbon ninu won, eyi ti ko ba toju owo fun ojo ale maa n ba ara won nibi ti won ko fe eleyii si le fa ibanuji pupo fun won. Ni tooto, won feran ariya sise, afefeyeye, ati se-a-ri-mi ninu ohun gbogbo, sugbon o maa n fa ota pupo ba won awon gan-an maa tun fi eniyan se eleya. Olooto eniyan ni won, won si tuwoka pupopupo, sugbon iwa bi ti omode kii saaba kuro ninu ise won titi di ojo ogbo tabi ojo iku, eniyan ti ijade re jo ni loju ti o si dabi oba tabi ijoye kan pataki ni igba gbogbo ni won, won si feran lati maa ba eniyan se awada tabi efe titi won o fi darugbo. IRAWO RE PELU ISE ASELA RE Okurin ni o maa saaba je arole fun won, won kii ni suuru to nkan, sugbon o di dandan fun won lati maa se suuru fun eniyan ati ninu gbogbo nkan ti won ba n se. Ti ayipada ba de si won ni buburu, ki won mu okanle giri, ki won si maa ke pe Oluwa pelu adura. Oluwa yoo si gba won ninu isoro naa. Ki won ma se fi eniyan se igbekele ara won rara. Kaka bee ki won gbekele Olorun Oga Ogo patapata. Oogun dudu ko ba won lara mu rara, bi eni pe won fi owo sofo ni yoo je fun won, afin kan ti o jemo eto adura. Won yoo je eniyan ti yoo ni aapon ati emi itara pupo, gbogbo awon ti won bo si je ore ati ojulumo won ni yoo maa gbadun iwa rere ati owo lila won. Gbogbo aso ti awo re tan lokeere ti o si fa ni mora gidigidi ni won yoo maa lo nigba gbogbo. Ohun elo olowo gege ti o si je eyi ti a le sope o dara julo ni a o maa saaba ri pelu won. Won kii se beniyan ti o faramo ohunkohun ti eniyan le da he re tabi ti a le so pe ko dara to. A da won lati maa se ori ninu ohun gbogbo, won si je eniyan ti won feran lati maa se eto ohun gbogbo. Won je eni ti awon eniyan maa n bu ola ati owo fun. Won ni ife omo pupo ju bi o ti ye lo, won kii saaba bi omo pupo, sugbon nipa iwa won, omo nkii feran won. Mo ro won ki won maa fa eniyan mora nitori ara eniyan ni ire won wa, ki won ma le eniyan sehin lara won. Won ni emi esin gidigidi, gbogbo eko ti o ba si je mo esin tabi ti eko ijinle ati ti oye ni okan won yoo maa fa si. Won feran ere sise, sugbon won ko feran odi yiyan, bi o tile je pe ètahoro won ni orikunkun ti yoo ti won kan abuku ati ètè. Won ni ife oso sise ninu ile ati ara, won si feran eran jije pelu. Mo gba won ni imoran pe ki won ma je eran pupo nitori oju sisu ati aisan inarun. Won ni emi igboya, sugbon obinrin won gbodo sora fun oso sise ki iwa naa ma ko gbese ba won, ki won ma ba ara won de ibi ti ko ye. Ki won ma se afowofa lati ba ibi daradara je fun ara won nipa inakuna. IKILO : Mo feran yin leti owe kan ti o wi pe ‘’igberaga lo n siwaju iparun’’ idi eyi nipe igberaga ni o buru julo ninu iwa aleebu re, lehin naa, o ni lati gbiyanju lati bori iwa ole ati fifi nkan ti o ye ki o se loni di ojo miiran, iwa ijora-eni-loju a maa di orikunkun ati aigboran. Faari aseju a si maa di ogo-asan, ma gbiyanju lati lo agbara ajulo lori eni keni, o le iwa imo-tara-eni-nikan. Gbogbo iwa wonyii ko le mu iranlowo kan wa fun o bi ko se pe ki o so o di alabuku, ki o si fa isubu tabi iparun patapata ba o sora pelu awon iwa aleebu wonyii, ma si sefi ikanju lo ile aye. Ma se fi eni ti o ba wa ninu isoro ati ibanuje IRAWO RE PELU ISE ASELA RE se efe tabi yeye bi ko se pe ki o maa mu inu won dun, ma se ba eni keni jiyan lori oro ti ko nillari. Yago fun aso, agbere ati aroka, ki o si sora fun emi iyemeji, se okan re giri lori ipinnu kan. Fi okan re bale nitori aisan eje riru (hypertension), ki o ma si jo ara re loju rara. ILERA : Aisan oju, iba, ara riro, ori fifo, iko ati inu rirun wopo fun won. Ju gbogbo re jo, oju didun ni o se pataki fun won. ISE: Ise ti o dara fun won niwonyii: Ise Imo Ero lorisirisi ona ( Engineering), Electiriki,, Hoteeli, Owo, Akowe oja, Akowe ijoba. Agbe sise, Adie sinsin, Oluko, Orin kiko ati isiro Owo (Accountanney) IGBEYAWO : Awon irawo ti o ba won mu niyii : Leo, Sagittarius, Scopion ati Aries. Won le fe irawo miiran pelu adura ati suuru, ki won le ba ara won gbe kanrin kese. Ojo ti o dara fun won ni ojo Monday. Nomba oriire won ni 1, 10, 19, 29, awo ti o si ba won lara mu ni pu pa roro (red) pupa resuresu (pink) ati pupa to ni ofeefee ninu (orange). Maleeka ti a si fi se eda won ni ina. Ki obinrin Leo sora lati ma se fi iwa mo gbontan, mo-mo-on-tan se gbogbo nkan, ki won si maa gba imoran ni akoko isoro won. VIRGO Vierge AUGUST 24- SEPTEMBER 22 Oruko Irawo akoko yii ni ‘’Virgo’’ Omo ti a ba bi lati August 24 titi de September 22 yoo je eni ti o le sise pupo, yoo si ni itara si ise ti won ba dawole lati se. Awon eni naa yoo je olooto ati olufokansin, eni ti ori re yoo ya si iwa Nigba miiran eewe, won yoo huwa ti o yato si iwa won tele ati nigba miiran, won yoo dake so ohun ti ko ye ki won dake si. Awon eniyan wonyii yoo feran awon ebi won lopolopo, won yoo si feran lati maa ran awon omo won lowo ninu eko won lati le je eniyan nla lolo ola. Gbogbo ipa ni won maa n sa fun awon omo won, won si feran lati se koriya fun ise ile Olorun. Ni akotan, won feran lati maa josin ni ile Olorun. IRAWO RE PELU ISE ASELA RE Won yoo je eniyan ti a fun ni ebun ogbon ati oye; won ni ilera ati ara to da sasa. Iwulo won ninu ile isin fun awon elomiiran nje abuda won, bayo nitori eyi ni pupo ninu awon omo Virgo se maa n sise ninu ile Olorun tabi nibi itoju awon eniyan. Igbesi aye won yoo je ise riran tabi riri ise ti a ran gba, gege bi awon omo miioran ti a n pe ni Gemini, eyi ti o je wi pe irawo kanna yii lo n joba won. Won le sise ni ile ifiwe ranse ti a n pe ni ‘Post Office’ tabi ki won sise iranse lona kan tabi omiran. Won je eda ti o feran imototo pupo, won ni ife si ere idaraya (sports) won si maa saaba ni ife si ati ran awon elomiiran lowo ni orisirisi ona. Irawo yii ko fun won ni igboya lati je asiwaju ninu ohunkohun sugbon ni igba pupo won je omo ehin ti o gbon lopolopo, ti ogbon won si je eyi ti o wulo fun asiwaju. Won je eniyan ti o maa n fi agbara sise, won si ni amojuto ohun gbogbo. Bakan naa, won je eni ti o maa n ronu jinle lori ohun gbogbo, ko ni je iwa won lati maa fi inufufu nse nkan. Won je eniyan ti ko ni maa soro pupo lati yi ara won si iru ipo kipo yowu ti kadara ba gbe de, won si ni okan igboya ti won ba fe se nkan. Sugbon ti won ba wi pe awon ko se kinni kan mo, won ko ni ya si idi nkan naa niyen. Won duro lori ipinnu won, won ko fe ki eniyan je opuro si won, won feran lati maa na ika aleebu si iwa eniyan. O maa n pe ki won to lowo, won maa nto eni ogogi odun ki ola won to yo nitorie elemi gigun ati olofintoto eniyan ni won ; nipa iwa igberaga die tio wa ninu iwa won, awon elomiiran a fe ki won se ohun ti won ko ba fe se nigba miiran. Gbogbo aisan ni o maa n yoju si won ti kii je ki won se nkan ti won fe. Ogooro awon ‘’Virgo’’ ni ko ni ogbon pupo sugbon won feran obinrin. Gbogbo ero okan je ilosiwaju, kii si se lori owo nini nikan bi ko se ebun ti Oluwa fun won. Abuda won ni lati maa fi inu han eniyan sugbon won kii fe se nkankan pelu bojuboju tabi aboosi rara. Won ko feran alabosi, ki nkan maa dan fun eni keni je okan ninu ero won laye. Won je eda ti o maa n so otito, won maa n so oju abe niko sugbon ki won sora fun orikunkun pe’emi ni mo da bayii’. Ipkokipo ti won ba wa, ki won maa se suuru, ki won ma se aseju nipa ohun kohun. Ki won ma se je a-nikan-jopon, ki won ma si fi inufufu le awon ore sa, ki won ma si rope eke ni gbogbo eniyan. Ki won sora fun ajeki ati oti mimu. Won gbodo sora fun igberara, ki won ma si jeki owo bowon loju, ki won sini arojine, won feran omobibi nitori ojo ogbo won, obinrin wona maa bimo ju okunrin won lo, won ko si feran agidi, ori won a maa gbona si alagidi, won ni orikunkun si nkan, won feran lati maa fi owo pamo sugbon ina apa ko jinna si won nigba miiran. ILERA : Inu rirun, ara riro, eforie, ehun didun ati eje riru a maa saaba se won. IRAWO RE PELU ISE ASELA RE ISE : Oja tita lorisirisi ona, ounje tita, ise ti o pa eniyan lokan po ati nkan oso ara, ise agbe, ile kiko, oluko ati alagbase. IGBEYAWO : Awon irawo ti o ba won mu niyii : Capricon, Taurus, Virgo ati irawo miiran ti won ba le kun fun adura ati suuru. Ile ni won fi se eda won, ojo orire won si ni Wednesday. Nomba orire won ni 5, 14, 23. LEBRA SEPTEMBER 24 - OCTOBER 22 Oruko irawo yii ni ‘Libra’ Omo ti a ba lati September 24 titi de October 23 yoo je eni ti suuru re po ti kii si tete binu. Omo ti o see ba da nkan po, yoo je alaanu eniyan fun obi ati eniyan gbogbo pelu. Won yoo si je onidajo ododo, yoo si feran aso wiwo ati oso sise. Won a maa se orikunkun si gbogbo nkan, won je eni ti won maa o puro nkan ti won ko se . Won si gbodo maa sora fun iwa won, ki awon eniyan ma baa mu won ni ota. Ki won maa sora nipa oro ogun ki o maa lofa ota ba won. Abuda won je eyi ti o tu ni lara, won si je eni ti o saaba maa rerin muse, itura ati anfaani nlanlaa ni yoo je lati maa bai ru won kegbe. Olorun fun won ni ebun oju-ona pupo, eyi je ki won tayo elegbe won, ti won maa saaba je oga ninu ise ona sise. Won je eniyan ti maa n fe irepo ati alafia nigba gbogbo eyi yoo si mu ki awon eniyan feran lati ba won sore. Bakan naa, won je eniyan ti o ni ogbon éwé paapaa julo iru eyi ti eniyan le ti owo re le te ohun ti o nfe lai fi agbara tabi ja se e. Won je eniyan ti won kii fe farada isoro ti o ba de ba won ati pe won tile ni ehun iyebiye lati tete maa gba kaamu ninu ipko kipko tabi isele ti o ba de ba won. Won si tun ni imoran lati maa fa elomiran yo ninu iwa buburu ati rudu rudu. Won a si maa feran lati maa be elomiran kegbe, ajorinpo je iwa ti o jinle ninu iwa won pupo, won si feran lati maa wo aso daradara. Won je eniyan ti o ni arojinle ti o si tete n fi oju-inu wo nkan pupo. Nigba miran, o seese ki won mo ohun ti o wa ni okan elomiiran tabi ohun ti o seese ki o sele lori oro kan. Won korira iwa ika, ko si si ohun naa ti o le mu won ba eni ti o ba huwa ibi gbe po. IRAWO RE PELU ISE ASELA RE Suuru ni ki won maa ni si oro ebi ati fun awon omo won pelu. Suuru ni aye won gba, ki won si sora fun ojukokoro ; ti won ba ni owo die ki won ma gbe e le onijibiti tabi awon so-ogun-di-ogoji lowo lati ba won se owo papo. Awon eniyan wonyii yoo lu won ni jibiti ni. Won ko gbodo fi inu han ore, ki won si sora fun ogun dudu, elada won kii se ogun dudu, adura ati nkan adura ni oro aye won gba, ki won si maa se iranlowo fun awon ti Olorun baran won si ki won si maa fi suuru ko eniyan mora. Sora fun isolenu ati igberaga ti eba ti ni owo lowo die, e si maa ngba imoran; e sora fun oti ati siga mimu ki won ma baa ba tiyin je nigba ogbo yin ati ki won ma so yin di eniyan yepere laarin ebi, egbe ati ogba. Awon omo ti a bi ninu osu yii maa n ran omonikeji lowo, awon omo won si maa n lakaka lati ri npe ko si ede aiyerede laarin ebi ati eniyan gbogbo. Won ni emi igbagbo, emi yii ni o maa ninu won nigba gbogbo, won feran lati maa josin pupo to bee ge ti okan won ko jinna si ife Olorun. Eyi je won logun nigba miran bi ogun kan ba dide si won, iru eyi ti o le gbe awon elomiran mi patapata, n se ni Olorun yoo fun won ni agbara ti yoo mu jade kuro ninu re laisi ipalara. Irepo je okan ninu awon ohun ti yoo maa mu anfaani wa fun won julo. Won yoo maa ni ire ati anfaani pupo nipa ajosepo. Eniyan ti o ni suuru pupo ti oferan ija rara ni won. Won kii fe maa di eniyan sinu fun igba pipe. Bi won ba ba eni kan ja, idaamu okan ni yoo je fun won titi ija naa yoo fi pari. Won kii wa ona iparun fun elomiiran, won si ni aforiti ninu ohun gbogbo ni egbesi aye won. Ibinu won kii pe, ti won ba ti be won. Won feran irepo ati isokan lopolopo. Olorun fun won ni ogbon nipa oro siso, won a si maa fi oro ro ara won wo ki won to huwa si eni keni, won si korira ija tabi ireje ni ibikibi. Awon Libra miiran a maa fi iwa jo iya won, won feran ohun oso ile ati ki ibi ti won ba n gbe maa mo tonitoni. A ro won ki won ma se maa ro ara won pin, igbehin won yoo dara fun nkan ti won ba n fe se; ki won ma se ilara elomiiran, ki won ma si gba ona eburu wa owo nitori Oluwa duroti won ninu idawole won. Ki won mojuto ise won, ki won si mojuto omo won pelu nitori iwakiwa, maa fi adura ran won lowo. Ma se ba omo re se orikunkun, maa ni suuru fun won, ma se maa fi ogun deruba eniyan, ki won ma baa so o lenu. ISE : Won ko ni fe duro nibi ise kan, eyi si le je ohun ti o le re won sile. Ise oluko (tescher), oniwaasu, adajo, oselu, agbe ati nkan esin dara fun won. IKILO: Ma se kuro mibikan lainidi Kan pato. Maa toju ohunkohun tii se tire, ma se faaji laisi ise, ki o si maa wo aso ti o dara ti o siba o lara mu. Kun fun IRAWO RE PELU ISE ASELA RE suuru, nipa eleyii ni iwo yoo segun. Sora fun oti mimu nitori aasiki ki adura re le maa gba. IGBEYEWO: Irawo ti o ba won mu ni Libra, Aquerius ati Gemini, won si le fe ninu awon irawo miiran pelu suuru ati adura. Won ko fe ki eniyan maa siregun le won lori. Afefe ni maleeka won. Ojo ti o dara fun orire won ni ojo Tuesday, nomba orire won ni 6, 10, 24. Awo ti o ba won mu ni pupa fo ati olomi bulu. SCORPION Scorpion OCTOBER 23- NOVEMBER 22 Oruko irawo akoko yii ni “Omo ti a ba bi lati October 23 titi de November 22 yoo je eni ti o ntenumo oro ti o ba fe, yoo si so o di ija bi eniyan ko ba gba tiwon, won yoo tun je olokan lile ati alagidi eda, bi ohun kan ba mu won binu, kiki asoju oro ni saa. Eni naa yoo je eni ti o feran ki won maa yin oun fun aseyori yowu ti oun ba se, iro pipa ki yoo si ninu iwa won bi o ti wu o kere mo, yoo si feran afarawe, sugbon eleyii maa n ko ba won. Bi ibinu won ba de, won yoo si feran otito siso. Iru eni bee yoo feran lati maa fi owo pamo ti eni kakan ko le mo nipa re, a si maa ro ehin, ologbon omo ni yoo je, yoo si mo iwe ti eniyan ba to o ni ile iwe. Won yoo je osonu, alagidi ati onroro eniyan, won yoo maa paro nigba miran, won je onibinu eda ti okan won maa nru, nigba miran, ko ni bikita lati maa fi agidi se nkan, nkan si maa njo won loju to be ge. Eniyan to ni igboya ni won, nitori idi eyi ni won maa n fi agidi se nkan. Alakikanju eniyan ni won lenu ise, won je eniyan ti won maa npa asiri mo pupo. Dajudaju, won je eniyan ti won maa nse ayewo okan si rere, eyi ti o si jo ni loju nipa abuda won ni wi pe. Yoo je eniyan ti okan re duro gboningbonin nipa ona yowu ti o ba te si ati lori ohunkohun ti o ba ni igbagbo ninu re ti o si faramo. Nihin yii sa, idaru okan le maa saaba wa fun un nitori pe iwa miran tu nbe ninu re ti o lodi si iwa idurosinsin ti mo wi yii. Idi eyi ni pe labe ase omi ni irawo yii wa ; gege bi iwo naa si ti mo pe omi ko duro ni oju kan soso bi kose ki o maa san sotun ati sosi tabi isoro lati se ipinnu kan pato lori ohun kan. IRAWO RE PELU ISE ASELA RE A fun won ni abuda ogbon ijinle, mo si rope nitori eyi ni awon amoye se fi ejo se okan ninu awon eranko to ba irawo yii mu. Gege bi o ti maa nfi tokantokan dura gboningbonin ti eniyan kan tabi ohun kan ti o ba n fe, bakan naa ni okan re yoo maa lepa ; nigba miran eewe, o le ri eni ti o korira, ti ko si fe tire tabi ohunkohun ti won ko fe. Iru awon omo ti a bi ni asiko yii feran lati maa je oniwaasu, ojogbon tabi onimo-ijinle ti ko see farawe, won a si maa jo ara loju pelu. Nigba miran, iwa areleke po fun won, won ko bikita fun nkankan, won feran lati maa wahala ara won, eleyii a si maa fa aisan rampe ba won nigba miiran. Isokiso ati esekuse maa n fa ipanun, awon si kundun iwa agbere pupo, ki won sora fun eleyii ; won ni ori ore pupo, won si maa n se ojurere fun opo eniyan, sugbon ibi ni opolopo fi nsan fun won, awon ota wa fun won pupopupo. Ni pataki, adura ni ki won kunfun, orè po ju ota won lo won feran lati maa soore sita ju ile lo. Alaanu eniyan ni won sugbon iwa agidi po fun won. Nigba miiran ti isoro ba de ba won, won maa n fi aya ran idanwo, won a gba a bii kadara, won si feran aso ati oso arasise pupo. Won maa n je eniyan Pataki ni igbesi aye won, ola ati itesiwaju wa fun won lojo gbogbo. Scorpion kii fe ki eni kan mo pe ara won ko da, won feran lati maa fi ara pamo nigba aisan, afi ti aisan naa ba po ju ni eniyan le mo. Awon Scorpion gba pe ore nigba iponju ni ore tooto, ki won sora fun iwa agidi sise. Igbesi aye won kun fun opolopo isoro sugbon nipa adura, won yoo bori. Oogun dudu ko ba kadara won mu afi nkan adura lilo nikan. Won je alaanu eda, won lawo si gbogbo eniyan, won si feran orin kiko. IKILO: Sora fun iwa agidi, inu-abiju, nini ipamora, orikunkun ati ai fe gba imoran elomiran. Iwa esan gbigba lara eni to ba se ni ati igberaga, awon nkan wonyi ko dara, gbiyanju lati ko ara reni ijanu lori awon iwa naa. Pa ahon re mo gidigidi ki o ma se soro ti o le pa eniyan lara. Bi kadara ko tile fe fi ojurere wo eniyan, o seese ki Oluwa ran e lowo nipa iwa rere. Sora fun iwa agbere nitori ki o ma ba kadara re je, eniyan le ko arun nipa isekuse. ILERA : Aisan ti o maa n yo won lenu ni iba, efori, ara riro nigba miiran, aisan won ko po ju eyi lo, ofowofa le da kun aisan won nipa isekuse. Won lojo aisan ti ara won ko ba da ISE : Ise ti o dara fun won ju ni ise ise Noosi (Nurse) aso ofi hihun, egbogi tita oluko, orun kiko, ise oko oju omi, won a ti feran ise agbe sisis pelu. IRAWO RE PELU ISE ASELA RE IGBEYAWO : Awon irawo ti o dara fun won ni Scorpion, pisces, Cancer ati awon irawo ti pelu adura ati suuru. Maleeka omi ni a fi se eda won. Ojo ti o dara fun won ju ni ojo satide (Saturday). Nomba orire won ni 9, 18, 27. Awon ti o ba won lara mu ju ni awo offeefee ati olomi bubu (yellow and blue). Sagittarius Sagitaire NOVEMBER 23 – DECEMBER 22 Oruko irawo akoko yii ni “Sagittarius” Omo ti a bi lati Nov 23 titi de December 22 yoo je olorire, gbajumo, olokiki ati akikanju ; eni ti o laayan ninu ohun gbogbo. Ero rere ni ero won nigba gbogbo, ohun rere ti won nlepa ki yoo sai to won lowo. Oninufufu ni won nigba miiran sugbon won yoo se bi eni ti ko ka nkan si to bee ge bi won ba pinnu lati se ohun kan, won kii gba imoran. Won ko ni fe dasi oro ti kii se tiwon. Irin ajO lilo ni won yoo yan laayo, idale se anfaani fun won, won ko ni fe ka eniyan si gege bi eni ti o le se nkan dara bi tire. Nigba miiran ohun kekere ni yoo so di ibinu ti yoo si ka a si ese si onitohun lorun, sugbon ibinu re ko ni maa pe rara, ko si le di oro sinu pelu. Iru awon omo bayii ko nii fe ki eni kan je gaba le awon lori tabi je alase fun won. Won ko si ni fe lati ba elomiiran da ise po rara. Ebun titayo ni eleda fun won, eyi ti ko fe je ki won o beru eni Kankan afi eni ti o ba bu ola fun won, eni ti yoo ko eniyan mora ni won, eyi yoo si je ki won ni ore pupo, won yoo si fe tete gbe iyawo pelu ikanju. Eleyii ni yoo je ki won maa ko iyawo sile tabi to ba je obinrin ni, yoo maa ko oko sile. Won a si maa ni oko pupo nitori won ko ni ni itelorun, suuru, ifarada ati iteriba. Won a maa ni ikanju si gbogbo nkan, emi igberaga a poju won lo, won a si feran lati maa fi ise kan sile se omiiran ; eyi ko si ni je ki gbogbo re ye won. Alaanu, alagidi, olorikunkun ati eni ti o kundun ounje ni won, koda, won le fi owo meweewa jeun paapaa. Won maa n wa ota fun ara won nipa iwa kiigbo-kiigba ati eeke eebu, won a maa jo ara won loju pupo. Won a tete maa wa ipo ola fun ara won lai le de ipo naa. Obinrin won ko ni fe gbe ile oko, bee ni okunrin won a feran obinrin. Igberaga ati okan-ile po ju fun won, won si feran lati maa se ise asekara. IRAWO RE PELU ISE ASELA RE Opolopo won lo maa n sise lai si ojusaaju, won si je eni ti o beru, ti o si gbekele Olorun, eyi mu ki won feran adura gbigba. Won si kundun eran jije ju awon nkan miiran lo. Bi aisan ba n se won, won kii saaba jeun. Aisan won maa n le bi eni pe yoo pa won, nitori won lojo aisan. Oloriire, alawada, ati oninawo eniyan ni won, won ni ife si awon eran osin pupo paapaa julo esin. Pupo ninu won tile seese ki o ni ife si ere esin sisa (horse-race). Bakan naa ni won ni ife si ere idaraya bi boolu-afese-gba, ere sisa, esin gigun ati beebee lo. Tafatafa ni won fi se amin irawo yii, nso okan ninu asiri ti o farasin nipa igbesi aye won pe won je eniyan ti o maa n fe rin irin-ajo lati ri orisirisi iriri, to ba si je nipa ti eko ni, won a tiraka lati ri npe won ka iwe de ibi ti won o ti gba oye imo-ijinle. Won je eda kan ti ara won ko lele ti won si n fe lati maa lo si ibi ti o jinna, won si feran lati maa ti ilukan lo si ilu miiran. Elero rere ni won, igba gbogbo ni ero okan won maan so tipe ojo ola yoo si dara ti isoro ba tile de ba won, igbagbo yii ki kuro lokan won. Lati igba ewe won titi won o fi to eni bi dundin logoji odun, iwa agidi, inu fufu, iyan jija, sise atako, ati fifi agidi die die lo emi itara ti won ni yoo maa wa fun won. Sugbon bi won ba se ndagba si , bee ni iwa won yoo maa yipada. Iwa ati ako won yoo dinku, won yio ni emi ifokansin, won si feran lati maa ko nkan meji po leekan soso, ibaa je ise tabi ohun miiran. O si seese ki ogooro won maa gbe bukata elomiiran mo tiwon. Wiwa ni eminira je ohun ti won ko le fi sere, won o si feran lati maa daabobo iyi won. Nipa ba yi bi eni keni ba gbiyanju lati fi abuku kan won tabi di won lowo lati wa ni ominira, logan ni won o fi suuru yago fun iru eniyan bee. IKILO : Ma se kanju nigba miiran ju bi o ti ye lo, ma si se pa ise kan ti tun bere omiiran, gbiyanju lati re ara re sile, ki o ma si fi oju rena elomiiran, gbiyanju lati re ara re sile, ki o ma sifi oju rena elomiiran ti ko ni ola to o. Ma se je ki oro kekere maa bi o ninu, yago fun ese kika si eniyan lorun, ma si se je ki o ya lenu ti eniyan ba gba or ore si odi ni igba miiran. Ma se r ope gbogbo ore ti o ba ni yoo feran re. Ma si se igberaga nitori ebun ogbon ti eleda fun o. Ma se ma nan owo ni ina-apa, sora ki o ma se fi inu han ore, won yioo ma da o, bee ni yoo fa ota fun o, ki won maa ba ba tire je ; maa se suuru ni gbogbo igba, ki o ma se kanju jaye, iparun ni yoo ma fun o, si sora fun igbona ara. Oogun dudu ko ba kadara re mu, adura ni gbogbo igba ati nkan adura sise dara fun o ju. Sora fun iwa olè sise nigba miiran, sora, ma se je ki a ba o nidi aboosi. Maleeka ina ni a fi se eda re, ojo ti o dara fun won ni Friday. Nomba ti o dara fun o ni yii 1, 3 , 12, 21, 30. Awo ti o ba won lara mu ni pupa roro (red) ati pupa to ni ofeefee ninu (Orange). IRAWO RE PELU ISE ASELA RE ILERA: Awon aisan ti yoo fe maa yo o lenu ni iba, lakuregbe, ara wiwo, otutu, ki o si sora nipa ifarapa kereke, nipa ijafara. Tun sora fun oti ati siga mimu, ki o ma baa ko aisan nipa mimu won. ISE : Awon ise ti o dara fun won ni ise iwaasu. Asiwaju esin Olorun, ise agbejoro (layer), oluko, oselu, agbe sise ati ise ti o le mu ki eniyan maa lo kiri laarin opo eniyan. IGBEYAWO : Awon irawo ti o ba won lara mu ni Leo, Aries, Sagittarius, won si le fe iyawo tabi ki obinrin mu oko ninu awon irawo miiran pelu opolopo adura ati suuru. CAPRICON DECEMBER 23- JANUARY 20 Oruko irawo akoko yii ni “Capricon” Omo ti a bi lati December 23 titi de January 20, yoo je eni ti yoo ma se nkan Pataki. Oro die ni yoo maa dun won, onitiji eniyan ni won, won ko ni nfe maa yoju si nkan ti ko kan won tabi nkan onikan; oninu rere eda si ni won pelu. Ojo aye won, ni owuro yoo kun fun wahala ati isoro sugbon nigba ti o ba di asale ni gbogbo igbesi aye won yoo wa maa dun yungba ti yoo si toro minimini bi omi a fowuro pon. Won je eniyan ti a fun ni ebun ogbon ati oye lopolopo, ohun gbogbo ti o ba si je mo ti emi tabi ifarasin, ni okan won yoo maa fa si. Eniyan ti o se pataki ti o si lagbara pupo, ni won je, okan won yoo le lori ohun ti won ba fe tabi eyi ti won ko fe. Won ko ni tete lowo titi yoo fi de idaji ojo aye won. Igbesi aye won kun fun wahala ati idaamu ni igba ewe won ; yoo dabi pe aye su won. Bi o tile je pe laasigbo po fun won ni ibere. Aseyori won a wa fi ara han lati omo ogoji odun tabi o le die ni gbogbo nkan yoo maa bere si ddara fun won. Nitori iya ti won ti je yii, won a maa toju gbogbo nkan ti won ni. Eni ti Olorun ba ran won si ni won yoo maa se loore, kii se pe iyan sa oogun gba nkan lowo, sugbon won ko fe alaseju eniyan, won hawo die, nkan kii pe su won, ti gbogbo eni won ba se loore ko ba dupe, to je ibi ni won fi su won, iru eni bee kii IRAWO RE PELU ISE ASELA RE saaba se oriire, adanu nii jasi fun won. Awon iyawo won yoo fe ko won sile lakoko isoro sugbon ti won ba se bee, abamo ni fun won. Igbesi aye won yoo je eyi ti o kun fun orisirisi ikuna, isoro, aini, ifoya, airise ati wahala. O seese ki won bere igbesi aye won pelu idiwo tabi ikuna, boya nipa iku obi tabi ailagbara to won lati ko won ni eko tabi ran won lowo bi o ti ye. Nigba miiran, aisan si le je ohun idiwo fun won. Nipa suuru, aforiti ati akiyesi ofin Olorun, bi o ti wu ki o koro to, sibe ayo. Iwa won je eyi ti o tutu to bee ge ti awon to ba sunmo won maa yoo maa beru won, won le maa ro o lokan won pe onigberaga tabi eniyan buburu ni won. Mo jerii si i pe eyi kii se bee rara ; abuda ati iwa won ni pe okan won lora pupo lati gba eni keni tabi ohun kohun wole lairo o jinle daradara. Beeni won ko le sare di ohun kohun mu, sugbon ohun ti a se akiyesi ni pe bi won ba di ohun kan mu tan a ti fi i sile ko ni seese mo. Bi won ba ni lowo, won yoo je eniyan ti o lawo pupo ti kii roju rara lati fi ti owo re sile fun ire ati iranlowo awon elomiiran. Won korira iwa asehan tabi se-ka-ri-mi to bee ti o je pe won kuku feran oore ti a se ni ikoko ju eyi ti a se ni gbangba lo. Awon ti yoo maa saaba ri oore gba lowo won julo ni awon ti o je dandan tabi ti won faramo julo. Bi won ti feran lati soore to, igba pupo ni won fe se, sugbon ti ko si lowo won, won korira gbese tabi ki won ra nkan awin, won ko fe bee nitori won ma iwon ara wo, won ko fe nkan ti o le mu okan won daru nigba gbogbo. Bi won ba binu si eniyan onitohun yoo jebi Oluwa nitori won kii tete binu ; won ko fe ki eniyan maa siregun le won lori, ti won ba binu kii tete tan ninu won ; won je alaanu eniyan ti won maa n gboro elomiran ro. Gbogbo aini eniyan maa n je ibanuje fun won, won si maa nfa eniyan goke ninu idanwo re. Okurin won maa nfe ju iyawo kan lo nitori ojo ogbo won. Won fe maa bimo pupo ki won le je oluranlowo fun won nigba ogbo. Elemi gigun ni Oluwa da won. Ti won ko ba fi ona eburu tete ri owo, odi gba lehin ogoji odun ni opolopo won to maa n lowo, tiwon kii se aro ojo bi ti awon miiran. Mo ro won ki won ma banuje boya ti wahala ba de ba won, ki won turaka, ko si ohun to le ti kii re, ki won saa ma gbadura. Won je eniyan ti o ni iwa rere ati emi esin, won si feran orin mimo, ka saa wi pe orin didun ni saaba mu inu won dun nigba ti ibanuje ati wahala ba de, o seese ki won ni ebun orin kiko tabi lilo ohun elo orin. Won je eniyan ti a fun ni ebun Pataki nipa agbara ati igboya lati maa se asiwaju ati olori awon eniyan pupo. Opolopo ire ati anfaani ni yoo wa fun won nipa akojopo eniyan. Iwa won ni lati duro ti oro won, laakaye ati oye won kun pupo, a si da won lati maa mu itunu, ayo igbagbo ati ireti wa si okan awon elomiiran nigba ti IRAWO RE PELU ISE ASELA RE won ba wa ninu idanwo. Eleda fun won ni ebun lati maa se eto ohun gbogbo lona to dara ti o si se tele. Eyi yoo saaba maa gbe won de ipo ola. Nigba pupo ni ri npe kadara yo maa gbe eru awon elomiiran le won lori, sugbon ki awon irawo yii gan an paapaa je eni ti o ti mura tan lati gbe iru eru bee. Ki won ma se fi inu han eni keni ni igbesi aye won, nitori eleyii ni yoo fa wahala ba won. Won ni anu iyawo won lopolopo to ba je oni suuru ni. Obinrin awon ‘’Capricon’’ a maa saaba da gbe nitori won ko ni ori oko, won si ni ife omo pupo. Obinrin ni saaba je akobi won, omo rere si ni won maa n bi pelu, sugbon ki won gbiyanju lati maa ko omo won ni ilana Olorun. Won ko feran oore asehan rara, won ni ife ile kiko ju gbogbo nkan lo, ko si ibi ti won ko le gbe, nitori ibi gbogbo ni ile owo fun won. Won ni itiju eniyan gbogbo, won n bowo fun eni keni, won ko ni igberaga lori gbogbo ohun ti Olorun ba se fun won. Awon irawo wonyii korira ija tabi fifi agidi gba nkan lowo eni afi bi o ba je pelu suuru. Won si korira ki eniyan gba ohun kan lowo won ki o ma lo nkan naa daradara. Won ko fe ki eniyan maa da won da bukata re saa ni gbogbo igba, tabi gba nkan lowo won nigba gbogbo, eleyii kii pe su won. Won korira gbese, won si lodi si Iwa aisooto tabi opuro eniyan. Ti eniyan ba je elooto, ko si nkan ti won ko le se fun onitohun. Won kii gba eniyan gbo afi ki won fi oju ara won ri i nitori gbogbo nkan ti won ba lero pe a seese ni won maa nba ijakule pade. Agbekele won lori eniyan maa nja si pabo fun won ni. Won je eku-werewere eniyan, won ko si ni ife obinrin to bee ge ki won o yan ale sugbon won feran lati maa reti ere ohun kohun ti won ba nawo si. Ninu iwa won, won ko ka ogun jije si nkan afi ohun ti a ba yooda re fun won. Alaanu eda ni won, a fi tire sile gbo teni eleni ti won kii boju wo ehin, ti won ba a se iranlowo fun eni keni won ko ka si bukata bee ni won kii si wa ile aye maya rara. Won ti gbagbo wi pe ohun aye yii yoo ba aye lo, ko si nkan ti a mu wa si aye yi, ko si si nkan ti a o mu lo. Ti won nba ta eniyan lore, won kii fi siregun tabi ki won gba a pada tinja ba de leyin ola. Won maa n fa eni ti o ba she won le Olorun lowo won ko ni fi iya je onitohun lowo ara won bi o ti wu ki agbara o ti wa lowo won to. Ko si eni ti o se won ki o ma jiya ese naa lodo Olorun, abamo ni ero eni ti o ba se won maa n ja si. Igbesi aye eni ti o ba se won kii dara mo. Awon ti a ba bi ni asiko naa pupo lati se, nitori iseda meji ni Oluwa fi se won ( ile ati Iyanrin). Won je eniyan ti o feran ise pupo, afe-aye kii se tiwon Ibi ti won ba wa, pelu ekukaka ni eniyan fi le mo pe eni kan wa nibe. Won kii kanju si nkankan, aisan ara po ju fun won ti kii fe je ki won se nkan ti won n fe, bee ni kadara won ko ba eniyan da ise tabi owo po bi o ti wu o kere mo. IRAWO RE PELU ISE ASELA RE IKILO : Ma se je alagidi, olorikunkun ati anikanjopon, ki o ma si se fi oro kereke binu ; o dara ki o gbekele Olorun ju eniyan lo. Gbiyanju ki o ko ara re ni ijanu lati ma se fi ise kekere sile lo se nla ; ki oma si se banuje tati maa ronu (glomy) nigba gbogbo. Pele ni ki o maa fi lo ile aye re, nitori eso pele ni ejo ngun igi agbon. Ma se ba eniyan da owo po nitori adanu ni yoo je fun o. oluwa ti da o ni eni ola ti ota ko le dena re lae. Iwo ni yoo bori ota-kota to ba dide si o. mo gba irawo wonyii ni iyanju lati ma se kegbe oti mimu lehijn adota odun. Mo ro won ki won sora fun iwa aisooto, ki won ma si se gba iyawo oniyawo ki o ma baa di wahala si won lorun. Ki won ma se di eniyan sinu tabi gbesan lara eni keni ti o ba se won, ki won si maa ro ero daradara ninu gbogbo nnkan ti won ba n se. Adura ni oro igbesi aye won gba. Ki won kun fun adura ni igba gbogbo, ki won si sora fun onijibiti eda lati ma fi dudu gba funfun lowo won. Oluwa yoo gbe won leke ota won. Ki won saa maa ranti nigba gbogbo pe bi oju eda ti wu ki o pon to laye yii, o si n bo wa dara. Bi ekun tile pe di ale kan, dajudaju ayo nbo lowuro. ILERA : Aisan won ni eti didun, efori, jedijedi, lakuregbe, giri, kuruna, ehin didun. Eje riru le gba ona eburu wole ti won ba nronu pupo, ki won maa sora nitori ifarapa, eleyii ko si fa ipaya rara. Ki won saa maa gbadura, Oluwa yoo daabo bo won bi o tile je pe oniruuru aisan ara po fun won. ISE : Awon ise ti o dara fun won ni owo, mekaniki (mechanie) iwe kika, ise ti o pa eniyan lokan po, ti ko ni je ki eniyan ronu. Owo moto, ise tete kii se ona won. Ise titan kan adura, adajo, agbejoro, owo alajapa ( ki won ra oja ni ilu kan lo si ekeji) ati ki won maa se ere tiata ( theatre) lokunrin ati lobinrin. IGBEYAWO : Capricon, Taurus, Virgo ati irawo miiran pelu adura ati suuru. Ile ati Yanrin ni a fi se eda won. Ojo ti o dara fun won julo ni ojo Monday. Awo ti o si ba won lara mu ni awo eweko (green) ati pupa resuresu (pink). Nomba oriire won niyii : 1, 3, 8, 17 ati 26. Pool tabi loto ti won ba n ta. IRAWO RE PELU ISE ASELA RE AQUARIUS Verseau January 21 - February 20 Oruko irawo akoko yii ni’’aquarius omo tia ba bi lati january 21 ti de february 2O yoo je eniya jee jee yoo si kun fun ogbon ati imo eko pupo, bia ba to o si ona eko, yoo je olokiki, yoo si feran lati man da si oro ilu tabi je oselu. Awon omo ti a nsoro re yii je eniyant ti yoo maa gbero bi aye won yoo ti dara nigba gbogbo. Irawo ti o njoba won ni URANUS (uranuos) Abuda won yoo je eyi ti o kun fun agbara wara-n-se se tabi iwa girimokai nitori gbogbo nkan ti won ba nse ni o maa ndara loju won. Nigba miiran ti won ba n sure. Okan won a sadede baje nitori oro ara ati igbesi aye maa su won, won si feran otito sugbon awon eniya maa ti won si aisooto. Won ferun orin olohun, won si ni eran ikorira lara; idi ni yi ti won eniyan fi man gba oro won sodi nigba miran : Awon eniyan ti a bi ni akoko ti a yii je, eni ti yoo feran ominira pupo sgbon igba pupo ni ihuwasi won yoo je eyi ti o le mn bi eniyan ninu gidigidi : ogooro won je dahunse, babalawo tabi onisegun !bi ko se won yoo ma da nikan nse lai fe tele apeere ti owon elomiiran : bio tile je pe orikunkun po fun won , ti eleyi si fa ti won fi nse ara won ; eyi je won logun, sibesibe won maa ntele imoran awon elomiiran nigba miiran ju ti ara won lo. Bi won ba wa laarin ogunlogo eniyan, ero ati ise won man n samba yato pupopupo si ti awon elomiiran. O seese ki won je eniyan ti okan re maa n lodi si lilo ase ati agbara lori olomiiran, eyi nipe yoo je olorikunkun si ase awon ti a pe ni alase. Agidi okan won po to bee ge ti won kii fe ki eni keni lo agbara tabi ase lori won. Bi inu won ti se dara to bee ni won buru to, amo sa won je eni kan ti won fe lati maa gba eniyan sile nipase ilana adura (spiritual healer). Awon obinrin ti a bi ninu osu yii n rewa pupo sugbon won feran lati maa toju omo won ni ile, Eniyan tutu ni won je ni ile oko won korira iwa koko-koko, oju kan lada nni ni won olorire ni won lojo ale won sugbon won ni ojukokoro ise sise. Won a maa ti ise kan de ekeji ni. Won feran lati maa so ero okan won jade fun elomiiran lai ohun kohun pamo rara. Awon ore yoo maa fie sun kan won pe oniwa wonran-wonran ni won, won si je alaapon eniyan ti yoo maa fe ilosiwaju gidigidi sugbon opolopo igba ni won o maa se nkan pelu asise nitori pe eniyan ti ara re ko bale ni won je. Iwa ati kedara won ni iwa rere. Irawo iwa rere ni o maa n tan si okunkun aye won, awon miiran feran ona buburu lati gba lowo sugbon ti ona rere lo po ju. Won ni ebun esotele Emi-mimo sugbon die ninu won feran emi okunkun. IRAWO RE PELU ISE ASELA RE Won a maa wa pelu ifura, igbakungba ni igbesi aye won maa n su won ti won ba wa ninu wahala tabi isoro. Pelu adura ni won fi a bori isoso won, nkanti a ri ni pe won jinle ninu iwa won pupo ju ife lati wa ni iminira ara won lo, bi won ko ba se eyi, yoo fedi ilosiwaju won lowo. Bi eniyan ba fi oju buburu wo won ninu aye won, won kii ba ara je, ki won tubo ko bi a tii huwa rere, ki won si maa se rere si eniyan, ko dara ki won ma ja tabi yan eniyan lodi. O dara ki won nmaa tujuka si eniyan ju ki won maa dinu lo nitori ki won maa tun so won lenu. ko dara ki won maa ba eniyan da ise po ati ki won maa, se ise ara won , won si gbodo ko bi a ti se nlo ogbon ori tiwon ju ki won maa lo ogbon ologbon awon omo ti a bi ni asiko yii maa n ni ife si awon ore won sugbon awon ore ma a n da won. Ki won ko bi a ti n da si oro. Ki won ma maa di tabi wugbo, apeere ori buruku ni eyi je fun won. Bi won ti feran egbe ati ogba to, iyalenu lo je fun wape igba pupo ni awon eniyan maa n korira won, eyi lo je ki ota po fun won. Oni sure eniyan ni won sugbon ko si igbekele kankan ninu won, nitori ibi ti eniyan ba ti won si ni won maa n te si. Bio tile je pe won ni arojinle, won ko se tele nitori oro won ko duro nibikan. Bi won gba ona kan lonii, o seese ki won yi biri lola, ki won mu ona miiran pon. Won je eniyan ti o feran imo pupo, eyi si le mu ki won ma le tele ona esin kan pato, nitori pe won korira ohun to ba le mu okan won sipaya, won o maa ri isipaya nigba gbogbo. Bi eniyan ba nwo oju won, yoo dabi imole lati orun wa. Awon isele ojiji yoo poju ni igbesi aye won, nigba pupo ni ire ati anfaani nla yoo maa yoju si won, lehin igba ti won ba ti so ireti nu. Aise deede, aimojutose ati iwa won le je ki igbesi aye won ya ni lenu pupo, nitori nigba miiran, won le sadede fi ore kan sile lojiji, ki won si ti ipa bee da eto won ru. Iwa aleebu won ni aisedeede, ainitelorun, ainifarada Kankan fun igba pipe an fifi orikunkun maa se atako eni ; ida agbara nbe lowo won, gbogbo iwa yii ni ailera won. Bi won ba n fe ilosiwaju, won gbodo je olotito. Bi won ba le lakaaka lati bori ailera won wonyii, isoro won yoo dinku. Bi isoro ba tile de, ki won ma se banuje, ki won turaka, oluwa yoo mu won bori. ILERA: Awon aisan wonyii ni yoo fe maa se won: aran; eje ruru; ara wiwo, ooyi-oju, ara riro ni keerikee, etori, lakuregbe ati oju didun. Nigba n won ba de idaji igbesi aye won, ki won sora fun awon aisan wonyii ki won ma baa bori won. ISE: Ise ti o dara fun won niwonyii: Noosi, aso reran, Dokita, owo sise egbogi tita, ise ina, akowe ati egbe. IRAWO RE PELU ISE ASELA RE IKILO: Ki won ma se lo siwaju alawo tabi yemiwo lati wadi ara won nipa bi ojo ola won yoo ti ri. Bi idanwo ba si de ba won eewe, ki won ma se ba ara je sugbon ki won mu okan le, nitori pe won yoo bori isoro naa. Bi won ba se ileri fun eniyan, ki won gbiyanju lati mu adehun se fun anfaani ara won. Ki won ma se ro ero buburu si ara won. Ki won ma ro ero nkan giga lasun ki ko se pe ki won tepa mo ise owo won, bi won ba si n lakaaka pelu adura, owo won yoo te ohun ti won ba n fe. Afefe ni a fi se eda won, ojo oriire won ni ojo jimo (Friday). Awo to ba won lara mu ni awo ofeefe ati olomi bulu (yellow jaune and blue bleu). Nomba oriire won niwonyii: 8, 17, 26. Awon irawo yii ni won le fe ni iyawo tabi oko: Aquarius, Gemini ati Libra. Ti won ba fe awon irawo miiran, won gbodo ni suuru ati adura IRAWO RE PELU ISE ASELA RE PIECES POISS0N (FEBRUARY 21 –MARCH 21) Oruko irawo yii ni ’’Pièces’’. Omo ti a ba bi ni February 21 titi de March 21 yoo je eni ti o feran awon egbe re, yoo je olokan funfun si eni keni. Nigba miiran, won yoo huwa rere tabi buburu ti awon alara ko le so idi re. Won feran lati ma gba imoran, won ni ebun eko, won a si jafafa bi won ba ni anfaani lati kawe, won kii fe ba eniyan jiyan. Awon irawo yii je oloto ati oniwa rere eniyan ti o se gbagbo ati eni ti eniyan le gbekele ni ipokipo ti won ba wa. Won feran lati maa ran awon ore won lowo nigba isoro, ni ogbon lati fi yanju oro to ba takoko, won kii saaba ba aniyan ja afi alasesa eniyan. Pieces feran lati maa josin si oluwa, won si feran adura pupo. Nini won ni a ti ri awon ti o ni imo orin kiko, won si je eni ti okan re maa n tete ru soke. Awon eniyan wonyii ni ebun ise ona tabi ise agbere sise. Won si ni ebun isipaya pelu. Okan ninu ebun ti o ga julo ti Olorun fi ta won lore ni eyi, yoo si je ki o rorun fun won lati maa fi ohun gbogbo to n bo wa sele yala si won tabi si elomiiran. Awon irawa wonyii je eda kan ti nwon ni arojinle ohun gbogbo lati fi apeere rere lele fun awon domiran lati maa tele. Oju ini won yoo je eyi ti o riran pupo bakan naa si ni eti-inu won yoo gboran gan-an eyi yoo tile je ki won gbo ilu, yoo si mo ijo jo lopolopo. IWA ATI KADARA WON : Won je eniyan ti o maa n fi ara won si ipo owo ti won si maa n ko ara won ni janu. Bakan naa eewe won o wa ni imurasile nigba gbogbo lati maa fi ara won sin awon elomiiran. Awon asiwaju wa nipa imoye iranse fi ye wa pe irawo kan ti a n pe ni Jupiter paapaa ni agbara ati ase lori igbesi aye awon ti a bi labe irawo yii. Bi eyi ba ri bee, a je pe agbara ati ase irawo meji lo wa lori igbesi eye won. Jupiter yii yoo se won ni eniyan ti o ni oriire, ti o si je gbajumo, yoo si fun won ni ife lati maa wa ona bi igbesi aye won fi le gba dara si, won o si maa se aapon pupo lori ona yii. Ase irawo yii kan naa ni yoo maa ran won lowo lati de ipo giga, yoo tun mu won ni aisiki lona ti o gbogbo ati lati se won ni eniyan ti o ga to bee ti gbogbo eniyan yoo fi maa bu ola fun won. Gbogbo awon ebi, ere ati ojulumo won lati maa fi I sokan ni gbogbo igba pe iranlowo oju rere won ni awon irawo yii n fe julo nitori ohun gbogbo to na ti n sele ni igbesi aye won, irawo maa ni yoo maa ni apeere rere tabi buburu. Ni tooto, eniyan ti o beru isoro, wahala ati ijangbon ni won, o seese ki won tile maa sa kuro nibi kibi ti iru re ba ti n sele. Eyi ni yoo je ki amonran ati itonisina awon elomiiran je ohun ti won ka kun iyebiye, ti o si se pataki pupo fun won. Won o IRAWO RE PELU ISE ASELA RE je eniyan ti o maa n ri isipaya gba pupo, eyi si le se won ni opolopo ire laye won bi won ba mo iyi tabi riri re. Eniyan ti ara tete maa n rin ni won, won je oninuure ati alawada eniyan. IKILO : Gbogbo wa patapata gege bi eniyan kookan ni a ni iwa aleebu tiwa, bi awon yii ti je eniyan rere to, mo fe gba won ni niyanju lati maa sora fun iwa aisooto, irenije tabi itannije. Nigba miiran, gbigbe ero okan eni ga ju ohun ti owo le to, le e faa ki eniyan ba ijakule pade. Mo ro won lati ma se je alaroye ati oninakuna. Ti e ba ni owo, e sora fun awon eletan, awon a foju fe ni ma fokan fe ni. E ma si se fi inu han ore kankan ni igbesi aye yin. Ore ti e ko ba mo inure yoo ko ba yin ti e ba fi inu han won. IGBEYAWO: Irawo ti o ba won mu ni Pièces, Scorpion, Cancer tabi Aries. Won si le fe ninu awon irawo miran pelu adura ati suuru. Ojo oriire won ni ojo Wesday. Abela alawo purple ati green titan fun adura dara pupo. Nomba oriire won lati maa lo niyii 3, 12, 21 ati 36. Omi ni a fi se eda won, ki won sora nitori awon ota ikoko, ki won ma baa wa isubu ati ipalara fun won. ILERA: Aisan bi iba, otutu, efori ati aya didun ni yoo maa se won nigba ewe tabi ti won ba ni omo owo. ISE: Awon ise wonyii dara fun won, ise akowe, oti sise ati tita, oko oju irin, oko oju omi, egbogi pipo (pharmacy), ojise Olurun, owo sise tabi ki won da ile ise sile, oluka ati awon iseti o pa eniyan lokan po. IRAWO RE PELU ISE ASELA RE Oro imo nipa ala ti eniyan nla lojoojumo laarin osu 1. Ojo kinni osu, ala naa yoo yori si rere. 2. Ojo keji osu, ko si otito ninu ala ojo naa 3. Ojo keta osu, ala naa je eyi ti ko maa n se. 4. Ojo kerin osu, ala naa je ko di nnkan mu. 5. Ojo karun-un osu, ala ojo naa tun je ala ojo lasan 6. Ojo kefa osu, a ko gbodo ro ala ojo naa fun eniyan 7. Ojo keje osu, fi ala naa si okan nitori otito wa ninu re. 8. Ojo kejo osu, ala ojo naa nilati se laipe. 9. Ojo kesan-an osu, ala ojo naa nilati se kiakia. 10.Ojo kewa osu, ala ojo naa nilati je otito, o si gbodo yori si rere. 11.Ojo kokanlaa osu, imuse ala yii laarin ojo merin je dandan. 12.Ojo kejilaa osu, e o ri ohun ti yoo mu ala yi iwa si iranti nitori yoo se si edakeji, nitori bi a ba laa si buburu o le se si obinrin tabi okunrin lara. 13.Ojo ketalaa osu, ala ojo naa yoo se laisi aniani. 14.Ojo kerinlaa osu, ala ojo naa yoo se sugbon yoo pe. 15.Ojo keedogun osu, ala ojo naa nilati wa pelu re laarin osu kan. 16.Ojo kerindinlogun osu, ala ojo naa nilati se. 17.Ojo ketadinlogun osu, ma se ro ala ojo naa fun eni kankan titi yoo fi pe ojo meta. 18.Ojo kejidigun osu, sera ki o si gbe dura ki ala na aie se si rere. 19.Ojo kokandinlogun osu, fi ala ojo naa wu re nitori ohun rere at idannu ni. 20.Ogunjo osu, iwo yoo ri esi ala naa sugbon yoo to ojo merin. 21.Ojo kokanlegun, ko si otito ninu ala ojo naa. 22.Ojo kijilelegun osu, ni suuru fun ojo die, iwo yoo ri ibi ala naa yoo ja si. 23.Ojo ketalelogun osu, ala ojo naa yoo sise laarin ojo meta. 24.Ojo kerinlelogun osu, ala naa yoo fun o ni opolopo itelorun. 25.Ojo keedegbon osu, ala ojo naa yoo se laarin ojo meje tabi mesan. 26.Ojo kerindinlogbon osu, se akiyesi ala yii, yoo si je nnkan ti o se pataki fun o. 27.Ojo ketadinlogbon osu, opolopo itelorun yoo wa ninu ala yii. 28.Ojo kejidinlogbon osu, otito ni ala yii, yoo yori si ayo. 29.Ojo kekandinlogun osu, fi okan bale, ala yii yoo je otito. 30.Ojo Ogbon osu, ala ojo naa, nilati se ni owuro ojo naa. 31.Okanlelogbon osu, ala ojo naa kii se ala gidi, ala lasan-lasan ni i se. IRAWO RE PELU ISE ASELA RE ALAYE KADARA Eyin eniyan mi gbogbo, mo fe ki e ma pe kadara meta lo wa laye yii. (i) Kadara lati inu oyun (ii) Kadara lati owo ara eni bi irawo eda (iii) Kadara lati owo omo araye. Kadara kinni ti o je lati inu eje (inu oyun), eleyii lo buru ju ninu aye omo eda eniyan nitori pe ko si babalawo tabi onisegun ti o le wo arun naa san afi Olorun lati inu eje nni wo inu eran ara ati egungun eniyan lo. Ko si eda kan laye yii ti o le mu un kuro afi Olorin ati Jesu Kristi lo le wo karada buburu ti o ba eniyan waye yii lati inu eje san, ti yoo si yii i e pada si rere. Fun apeere Olorun lo yi kadara iponju Jabesi ^pada sir ere fun un. Kadara keji nje eyi ti eniyan paapaa yi ara re pada si I baa se rere tabi buburu. Eleyii ko ni gbongbo tabi ijinle kan ti o le fi idi mule. Ko lagbara pupo lati ba aye eniyan je, sugbon eniyan gbodo sora tabi ki o kiyesi ara re lori iwa buburu ti o n hu ati afarawe eniyan. Efa ko kiyesara nipa iwa re ni kadara buburu fi wonu aye re oun okore. Kadara keta ni Ayanmo ti ota, kadara lati owo omo araye. Imo tabi été ota ni ki a so eniyan oloriire di olori buburu tabi ki won o da eniyan ru patapata afi Olorun nikan lo le gba ni lowo ogun ota alayanle ti o n ba aye eniyan je. DIE NINU ASIRI IWA TI OMORAYE FI N BIMO 1-Ti obinrin ba loyun, ti o ba hun iwakiwa tabi fewo, eleyii fi han gbangba pe emo naa yoo maa jale ni aye re. Nigba ti Olorun da Adamu ati Efa saye tan, ti won si ti se ni kadara bubru nti wo inu aye omo eda. Iwa buburu ni Efa fi bi keni, lo fi ya apaniyan, ohun ti eniyan ba hu ni iwa ni yoo je kadara re. 2- Awon obi omo miiran wa ti o je pe kiki ija tabi ki won maa gbe omo ara won sepe lasiko oyun ati nigbakungba, o daju gbangba pe ipin ija ati epe ni won maa yan fun omo won. 3- Ogunlogo abiyamo ti fi iwa buburu bimo sile, iwa buburu naa lomo won yoo si maa nhu. Ko sadede ri bee, kadara iwa buburu ti won yan fun won ni. 4- Awon kadara ti omo ti ba pade lati inu eje lasiko oyun, awon wonyii le pupo ninu aye omo eda lati yipada. Afi Oluwa nikan lo le yii pada nitori pe Olurun nikan lo ni isegun ti o le wo iponju san. IRAWO RE PELU ISE ASELA RE 5- Igbesi aye ayanmo lati owo obi ni gbogbo omo eniyan n gbe patapata, nitori pe ti obi ba si iwa hu, afaimo ki omo won naa si ile aye gbe. 6- Eni ti won fi eje bogi-bope loyun re, bawo ni yoo ti se lesin Olorun ? Tabi omo ti won toro lowo esu, ko soro fun lati ya si ijo Olorun. 7- Omo ti won fi iwa pansaga tabi agbere bi si aye, lati kerekere ni yoo ti fi iwa jo obuko tabi aja awon ti won ba fi iwa agbere bi, irin regberegbe ko ni tan lese won laelae afi ti won ba tete fi ara won si abe akoso Olorun 8- Omo ti a fi iro ati eke bi, opuro tabi eleeke-eebu ni yoo ya. Melo ni ki a rohin ninu asiri iwa ti omo araye fi n bi omo won sinu aye ? Iru iwa wo lo n be lowo yin nigba ti e loyun omo yin ? Iru iwa naa lomo yin yoo maa hu to ba dele aye tan afi adura lo le yi I pada. 9- ki a bimo, ko omo naa se oriire ni iyi omo eniyan. Ki Oluwa fun gbogbo wa lomo rere bi sinu aye, ki Eleda fun wa leniyan iyi bi soke eepe. Ki Olorun fun gbogbo wa ni omo ti yoo gbeyin t’eyin se. KOKORO ASIRI EDA TI N FONA HAN NI 1- Bi obinrin ba n se nnkan osu tabi ri alejo re, ko gbodo je ki aso naa maa fi ara kan ogiri tabi iganna. Bi o ba n se bee bi osu naa ba pari, ti ohun pelu okore si lopo, ti osu naa ba duro lara re, ogiri ni yoo wo pa omo naa bi won ba bi i. 2- Bi obinrin ba loyun ti o balo nsan olo ata lati fi sebe, bi aboyun naa ba nse be ti a fi omi olo naa se, bi o ba bi omo naa, olo inu tabi osi ko ni je ki omo naa gbadun ojo aye re. 3- Bi obinrin ba loyun ti omo naa ba je okunrin, nigba ti a ba fe da iwo re, ki o je deede orunkun ti ko ba de orunkun re, omo naa ko ni le ba obinrin lo daradara, yoo maa re e ati pelu pe yoo si je eni ti aran yoo maa yo lenu nigba gbogbo. Bi o ba si tun wa koja orunkun re, yala okunrin ni tabi obinrin, yoo je okan ninu awon pansaga paraku. 4- Bi obinrin ba n se nnkan osu, ko gbodo fi owo re nu ewe, bi o balo se bee, lehin ti o ba pari nnkan osu naa, bi oun pelu oko re ba pade tabi lopo ti osu naa ba si duro si ni lara, iru omo bee lo maa nya ‘’ ko-gbele, ko-gbeta’’, yoo nsi maa hu iwa ipata ati ipanle kiri, ko si le ni ibujoko kan lode aye re rara, nitori naa ni obinrin se nilati kiyesara. 5- Bi obinrin ati oko re ba pade, ki won ma se je ki aso ti won ba n lo tabi fi tunrase kan ogiri (wall), bi o bal o fi ara kan ogiri, ti o ba si di oyun, bi won ba bi omo naa tan, ogiri ni yio wopa iru won. IRAWO RE PELU ISE ASELA RE 6- Bi obinrin ba n se nnkan osu, ko gbodo lo we lodo to n san tabi ki o fo aso naa, ki o da omire sinu agbara, bi o balo se bee ; bi osu naa ba duro lara re, ti won ba si bi omo naa tan, odo tabi agbara ojo ni yoo gbe e lo. 7- Bi obinrin ba ba okore ja, ti won ko fi inu didun ba ara won lopo, bi osu naa ba duro lara obinrin yii, ti won ba bimo naa tan, ko ni loju aanu rara, ko si ni ni emi idariji pee. Osonu ati alaigboran omo ni yoo ya. 8- Bi obinrin ba n fi ikunsinu pade oko re, ti o si maa n pose tabi yo kusi nu si okore, bi osu naa ba duro lara obinrin yii, ti o si bi omo naa, eni ètè ati alabuku ni yoo je. Bi o tile lowo, ko ni salai maa kan abuku ni igbesi aye re. 9- Bi obinrin ba n se nnkan osu lowo, ko gbodo je ki ekute je aso osu tabi ki o gbe e lo. Bi o ba ri bee ti osu naa ba duro lara obinrin naa, jaguda paali, ole tabi olosa ni omo ti o fi bi naa yoo je. 10A ko gbodo fi owo wo iwo omo ti a sese bi soke ki a to da a, bi a ba se bee, bi o ba je okunrin ni, ipake, ikunnu tabi ipa yoo ba omo naa ja. Bi o ba si je obinrin ni, arun inu rirun ko ni le je ki o bimo lode aye re. 11Obinrin tabi okunrin ko gbodo tuto tabi ki o woto danu nigba ti o ba dide lori obinrin tabi ki obinrin tuto nigba ti okunrin ba sese dide lori re, bi won ba se bee, bi obinrin naa ba sesi fi osu naa loyun, omo ti o ba bi naa yoo maa ku warapa ni. 12Bi Obinrin ba n se nnkan osu lowo tabi ti oyun ba wa ninu re, ko gbodo maa fi ibinu ko ohun kohun ti won ba fi ta a lore sile. Bi obinrin ba n se bee, amubo yoo po pupo fun omo ti won ba ti ati pelu yoo si ma se ‘’a-se-i-ri’. 13Bi obinrin ba loyun ti o sin bere dorikodo, omi mimu tabi ounje yoo maa fe si omo naa agbari tabi pa a lori, opo omo si le gba ibe di ero orun tabi se alaisi lai tii bi i. 14Obinrin ko gbodo ja ni akoko to nse nnkan osu lowo, ti o ba se bee, ti won ba na an ni pasan tabi oro enu, bi oun pelu oko tabi okunrin ba papo, ti o ba di oyun, bi won ba bi omo naa, iwa abaku tabi ètè ko le jina si iru omo bee. Bi o ba si se eni ti o dagba ju eni ti a le na lore, ko ni salai hu iwa agidi si ijoba ti won yoo si je e ni iya ti o doblu. 15Aboyun ko gbodo fi igba tabi awo ti o riri mu omi tabi ki o mu omi ti o doti, ti o ba bi omo naa tan, ko gbodo fi awo tabi paanu tiko mo jehun, ti o ba se bee, omo naa yoo ya oponu tabi pokii, ko si ni mowe. Bi won baran an nise, esekese ni yoo ti gbagbe, iru omo bee lo si nya omo radarada tabi dobosiyesa. Nitori naa, ki iya olomo kiyesara. IRAWO RE PELU ISE ASELA RE 16Obinrin to ba pari nnkan osu re to bi ojo meta tabi merin ti ko we ki o to lo ba okunrin lopo, ti o ba sesi di oyun, omo naa yoo ya adete lojo aye re. 17Bi obinrin ba n fi aso to mo se nnkan osu re, nigba ti o ba pari re, bi oun pelu okunrin ba lopo, ti o si di oyun, iru omo bee yoo je gbajumo, iru won ni a n pe ni omo aso, yoo maa loye ohun kohun, bi ko tile jeun ana sun, yoo maa ri owo fira aso saa ni, ko ni maa fi owo kan aso idoti rara. Bi o tile je aso meji lo ni, gbogbo igba ni yoo maa dan, iru won ni I ba maa marindoti. 18Bi obinrin ba n fi aso akisa se nnkan os ure, o ba si pari re tan, ti o si ba okunrin pade, ti o di oyun, bi won ra aso titun fun iru omo bee, yoo maa fa a ya ni. Akisa ni yoo maa wu u lati lo ju aso titun lo. Bi o ba dagba tan, bi owo ba tile wa lowo re, sesi ni aso to nilari kan le wa lara re, ko tile ni wu u wo ni. 19Bi obinrin ba n ba okore ja ijakadi ki won to maa lopo, bi o ba di oyun, bi won ba bi omo naa yoo je alagidi ati alajaigbila eniyan. Ki yoo ni emi idarijiba ni ko ni le bowo fun obi re, ko ni mo bi a ti nbu ola fun won. Iru awon obi re, ko ni mo bi a ti n bu ola fun won. Iru awon omo bee ni maa n rin kiri saa lode aye won, ti won yoo so ara won di alarinka. 20Obinrin ko gbodo toro ohun kohun lati lo fun omo ti a sese bi, ose, kaninkanin tabi omikiri ojule. Bi eyi ba lo ri bee, omo naa ko ni ni itiju lati toro ohun kohun rara, yoo si ti ipa bee di olojukokoro. Ni akotan, o le di alagbe ponmbele. 21Bi obinrin ba loyun, ko gbodo maa so pe iru omo bayi ni oun yoo bi yala okunrin ni tabi obinrin. Ki o ma se so okankan ninu re, bi o ba so pe obinrin ni ti o si lo ri bee, omo maa yoo yagan. Bi o ba je okunrin ni yoo ya okobo tabi ki o maa ba obinrin lopo lai le domo. 22Ka ni obinrin ri nkan osu re lanna, to ba paro fun oko re pe onii ni oun ri I tabi ijeta, bi o ba pari re ti oun pelu oko re si lopo, to ba di oyun, omo naa yoo ya opuro, otito ko ni si lenu re bi o tii wu o kere mo. 23Obinrin ko gbodo fi oja to dèra tabi ti o ti gbo pon omo, bi o baja mo omo naa lehin, abiku agba ni omo naa yoo je. 24Omo ko gbodo jabo lehin iya re, bi eyi ba ri bee, to ba se obinrin ni, iku oko meta tabi merin nbe fun iru omo bee, to ba se okunrin naa ni, iku aya meta tabi merin n be fun un. 25Bi obinrin ba pari nkan osu re ti oun pelu oko re ba fe pade, ko gbodo se sio tabi pe oko re ni oloriburuku, bi o ba ri bee, ti won ba pade ti IRAWO RE PELU ISE ASELA RE oyun si duro, eni abuku ati ètè ni omo naa yoo je lojo aye re. bi o ba tile ni owo lowo tabi o je oga ni ibi ise kan, won yoo maa fi abuku kan an saa ni. 26Bi obinrin ba loyun, ko gbodo jeko lenu ona tabi ki o maa yoju sode lenu ona nitori ojo ikunle re, bi eyi ba ri bee, bi alaboyun naa ba de ori ikunle tabi nrobi, omo naa ko ni tete wale, bi o ba si bi omo naa tan, yoo maa se’’oju-mi-tole, oju-mi-tode’’. 27Ti obinrin ba loyun, ko gbodo maa ki owo bo apo oko re lehin tabi ki o jale, ti o ba bi omo naa, ole ni yoo maa ja ati pe odaju ni yoo ya. 28Ti obinrin ba loyun, ko gbodo maa sun oorun asunju, ti o ba bimo pelu eyi, olè ; dindinrin ni omo tabi omugo ni yoo ya. 29Ti obinrin ba nse nnkan osu, ko dara ki okunrin o ba a lopo, okunrin ti o ba si se bee, gbogbo ona’’a-ti-je, a-ti-mu’’ re yoo daru raurau. Boya ni oun funra re a nilaari titi yoo fi ku, ti obinrin naa ba fi loyun, adete tabi afin ni yoo fi bi 30Ti obunrin ba loyun tan, ti o ba si tun n se isekuse, ti o ba bimo, odaju, janduku ati alailaanu omo ni yoo ya, yoo si pe ki o to nilaari. 31Bi okunrin ba ba obinrin aboyun ti kii se tire sun tabi lopo, yoo pe ki owo to duro lowo re, gbogbo nnkan to ba n se yoo ma ja sofo ni. KOKORO ASIRI AWA EDA TI A NILATI KIYESI 1- Bi eniyan ba ni irun ogoro lori, (irun to maa n hu si atari eniyan ti won n pe ni katamba), o fi han pe oluwa re ko ni nilaari li ojo aye re, bi a ba ju u sinu agba owo gan an, yoo so o di ile kedere ni. 2- Bi eniyan ba ni irun funfun tii maa hu si atari eniyan, bi ko ba mura daradara, ko ni le da nnkan rere se lode aye re ki o to lo. 3- Bi amin dudu, eyi ti o maa n han bayi(*), ba wa ni oke ipenpeju oun eniyan, eleyi fi han pe oluwa re yoo tete gbeyawo ti yoo ko oriire ran an, ti yoo si wa ni aisiki ti o ren. 4- Bi amin dudu ribiti naa ba si otun ni iwaju ori eniyan, paapaa ni apa otun, oluwa re yoo je oloro to bee ge ti okiki re yoo kan kaakiri. 5- Bi amin dudu naa ba si han ni ereke eniyan, ni apa otun tabi osi, oluwa re ki yoo je olowo, ko si ni je talaka, eyi tumo si borokinni. 6- Bi amin dudu yii ba wa ni ori imu eniyan, ojuwa re yoo ni oriire ninu idawole re, bi o ba n sowo, yoo maa ta ju ti elegbe re miiran lo. 7- Bi amin dudu naa ba han lara eeté eniyan li apa eke tabi isale, o nilati sora ki o ma baa bo sinu idewo, sugbon nipa oore sise, yoo ri isegun tabi oju rere Olorun. IRAWO RE PELU ISE ASELA RE 8- Bi amin dudu yii ba wa lara eniyan lode, o di igba ti oluwa re naa ba gbeyawo ki o to nio irorun lode ayere. 9- Bi amin dudu naa ba wa ahungbon eniyan, oluwa re yoo je alaisiki, yoo si de ipo nla lehin ola. 10Bi amin dudu ti a wi yii ba wa lara omo tabi oyun otun eniyan, o fi han pe omo obinrin ni yoo po ju ninu omore. Bi ko ba si mura daradara, iresile tabi ifaseyin yoo de si iru eniyan bee lojiji. 11Bi amin dudu naa ba wa lara omu osi, o fi han pe omokunrin ni yoo po ju ninu omo oluwa re ati pe yoo maa ri ibukun lori ohun kohun ti o ba dawole. 12Bi amin dudu yii ba han ni ookan aya eniyan, oluwa re yoo maa ni alaafia, yoo se oriire ni igbesi aye re, ki yoo si eru tabi ifoya fun rara. 13Bi amin dudu naa ba han ni ikun eniyan, oluwa re yoo je alajeki ati ole a rise ma se. 14Bi amin dudu yii ba wa ni itan otun eniyan, nikehin, oluwa re yoo di oloro, opo eniyan yoo maa bu ola fun, yoo si se oriire nipa igbeyawo. 15Bi amin dudu naa ba wa ni itan osi eniyan, oluwa re yoo se wahala lopolopo ni igbesi aye re, awon eniyan gan-an ko si ka a si pataki. 16Bi amin dudu yii ba wa ni orunkun osi eniyan, alaini ronu ati oni waduwadu eniyan ni yoo je, yoo si je olooto, oniwarere ati onisuuru eniyan. 17Bi amin dudu naa ba wa ni orunkun otun eniyan, oluwa re yoo se oriire nipa oro igbeyawo sugbon ko ni sai ba wahala die pade ni ode aye. 18Bi eniyan ba ni omo owo tabi ti ese mefa-mefa ti won n pe ni ahonon tabi olugbodi yoo ni agbara ati aisiki pupo pupo. Iru oja yio wu ki won maa ta, wara-wara ni bi eni se awure si ko, ise Olodumare ni. Gbogbo awon wonyii je akunleyan eda lati ode orun wa, ti oogun, ogede, aasan tabi ifa ko le yipada. Akiyesi - Wo igbesi aye Abrahamu ninu Genesis ori Kijilelogun ese keji de eketala (22 ;2-13). IRAWO RE PELU ISE ASELA RE AWON OJO TO BURU JU NINU O UN KOOKAN Mo wi fun yin, eyin omo iya mi ti o ni anfani lati ra iwe yii fun lilo laarin odede ati ijo eniyan Olorun, ki a ba la mo bi a o se yera fun ewu ti nbe niwaju wa. Ninu odun kan tii se otaleloodunrun ole marun-uu tabi mefa (365 days common year and 356 days leap year), ojo merindinla dorin to buru ju ninu osu kokan January 1, 2, 6, 11, 17, 18 February 8, 16, 17 March 1, 3, 12, 13, 15 April 1, 3, 15, 17, 18 May 8, 10, 17, 30 June 1, 7, 10 July 1, 5, 6 August 1, 3, 17, 20 Sept 1, 2, 15, 18, 30 October 15, 17 November 1, 7, 11 December 1, 7, 11 Ohun kohun to ba yoju tabi sele ninu won ojo wonni, ko si igbekele ti o daju Kankan fun nkan bee. 1- Bi eniyan ba se igbeyawo ni okan ninu awon ojo naa, ija, iponju ati wahala lo maa nje fun won, leke gbogbo re, ituka ni yoo gbehin re afi epe durs. 2- Bi eniyan ba bere ile kiko ni okan ninu awon ojo naa, orisirisi idanwo ni yoo ba pade. Bakan naa, ki eni keni ma se gbin ohun ogbin laarin re ki o ma baa dabi eni pe omulemofo ni yoo jasi ni igba ikore. Bi onitohun ba tile sesi ri nnkan ta ninu nnkan ogbin naa, afaimo kio ma fi wo aisan. 3- Bi eniyan ba bere irin-ajo oju omi ni okan ninu awon ojo wonyii, aisan ni iru eni bee maa nba bo tabi ki jamba se e. 4- Bi aisan ba kolu eniyan ni okan ninu awon ojo naa, ti opolopo lo njasi iku, etahoro lo maa nru u la. 5- Bi won ba si bi omo kan ninu ojo wonyii, yoo maa je alailera nigba gbogbo ati pelu kii se eni ti emi re le gun to bee, ju bee lo. 6- Mo si tun fi ye pe, bi awon ojo yii ti buru to nni, awon okan wa to buru julo ninu won, eyi tie mi ko fe ki eyin omo iya mi ninu Olorun se aigbaran si rara. Awon ojo naa niyii; March 3, August 17 ati September 1, 2, 30. Awon ojo maraarun yii ko dara. 7- Awon ojo to buru ju gbogbo re ninu awon ojo naa ati ohun ti o sele lojo naa ni wonyii: (i) April 1, eyi ni ojo ti won bi Judasi Iskariotu ti ise onikupani. (ii) Bakan naa ni osu August 1, ojo naa gan-an ni won le esu ti IRAWO RE PELU ISE ASELA RE nse Lusifer ati awon omo ogun re kuro ni orun. (iii) December 1, ojo yii ni Olodumare pa Sodomu ati Gommorra run. Bi eniyan ba pa nnkan tabi ta eje sile ni okan ninu awon ojo meteeta yii, oluwa re yio ku ki atori ojo meje tabi mejo. Omo ti won ba si bi ninu awon ojo meteeta yii yoo ku iku ojiji, yoo si je eni egan, ètè, alabuku ki o to fi aye sile. Akiyesi nla niyii fun eyin omo iya wa, ohun kohun yio wu a ba ni ki eniyan ma se, ki o ma se fi”aya-koko-inaki” se e rara. Iwe owe ori kejilelogun, ese keta Owe 22: O so bayii pe, Ologbon eniyan ti ri ibi tele, o si pa ara re mo, sugbon awon ope koja, a si je won niya. Nitori naa, e je ki oro inu iwe yii ye yin yekeyeke. ORO IMO NIPA TI AWON OMO TI A NBI 1- OJO SUNDAY Omo ti a ba bi ni ojo Sunday tabi ojo ose, yoo je alaisiki, olola, oninuure ati elemi gigun. 2- OJO MONDAY Omo ti a ba bi ni ojo Monday ki yoo si ilosiwaju deede fun un ninu idawole re ni ibere aye re bi o ti nfe, sugbon yoo je onirele ati oninurere to bee ti awon eniyan yoo fi maa re e je, sugbon nipa ebe ati adura, igbehin re yoo wa dara ju ti isaaju lo. 3- OJO TUESDAY Omo ti a ba bi ni ojo Tuesday yoo je omo lile ati oninu fufu. Bi o ba se okunrin ni, yoo feran lati maa se ijangbon. Ti awon obi re ko ba tete mura si oro re, yoo ko wahala ba won nipa iwa ati ise re, o le fa ijiya nla tabi iku ojiji ba ara re paapaa. 4- OJO WEDNESDAY Omo ti a ba bi ojo Wednesday yoo je omo lile ati olori aseta. Bi a fi si ileeko, yoo ni imo pupo, yoo si je olokiki ni igbesi aye re. Ise ko ni o dara fun iru won julo. 5- OJO THUNDAY Omo ti a ba bi ojo Thunday y o ni aisiki, ayo ati alaafia won daradra. Olola ati oloro ni yoo je ni igbesi aye re. Onigboya ni won, sugbon ota IRAWO RE PELU ISE ASELA RE maa n po fun won. Eyi ti o buru iu ni pe bi won ko ba kiyesara boya ni ina igbagbo won le jo geregere to bee ti won yoo ife Olorun titi opin aye won. 6- OJO FRIDAY Omo ti a ba bi ojo Friday yoo je alagidi, onijangbon ati oloriire, opuro ati oloro pupopupo.”A-baya-ko-bi-aara” ni won, won ki yoo dide fun egbe won jokoo, bee ni won ki yoo ri isoro ni ojo aye won. 7- OJO SATUDAY Omo ti a ba bi ojo Satuday yoo ri idanwo ati ibanuje die ni ibere ojo aye re. Gbogbo igba ni yoo maa se si ofin, yoo si maa jiya sugbon ni ikehin, yoo di olufokansin ati eniyan Olorun. Awon egbe ati agba ti o ju u lo yoo maa bu ola fun un, Oluwa yoo bukun fun nigbehin aye re, yoo si wa di olola ati oloro nla ni opin aye re. Nitori naa, eyin ara mi, e ma se wo oko a nda ifa tabi opele, ko si ere kankan nibe, Oluwa fi i si wa lokan lati se eyi fun eyin omo iya wa ninu Oluwa, lati kiyesara ati lati fi Olorun se igbekele yin. KOKORO ASIRI AMIN ARA AWA EDA 1- Bi atari re ba n yun tabi hun o ju bi o ti ye lo mo daju pe iwo yoo bo si ipo giga kan laipe. 2- Bi ipenpeju otun ba nyun tabi hun o, ki o mo pe iwo yoo ri ohun kan ti yoo dun mo o ninu tabi ki o ri ore re ri o ti lo si idale ni ojo pipe tabi ki ota re kan pada wa di ore. 3- Bi ipenpeju osi re ba nhun o, ki o mo pe iwo yoo ri ohun kan ti ko ni dun mo o ninu, bi oku ore re kan ni tabi ki isele buburu kan se, okan yoo sele nibe. 4- Bi eti re osi ba nho tabi o pariwo, ki o mo pe iwo yoo gbo iroyin buburu kan lati okeere wa. 5- Bi eti re otun ba nho yoo, ki o mo pe iwo gbo iroyin oye kan lati okeere wa. 6- Bi eti re osi ba nkun, ti o si tun npariwo ye e, ki o mo pe eni kan n soro re lehin ni buburu ni. 7- Bi inure ba nhun o pupo, mo daju pe oro ijangbon kan tabi ija nwa o bo wa ati pelu pe oro ibanuje ko jina si o, maa gbadura ki o si lo ni suuru. 8- Bi ejika re otun ba n hun o, mo daju pe ohun ayo kan nbo wa si odo re. IRAWO RE PELU ISE ASELA RE 9- Bi ejika re osi ba nhun o pupo, mo daju pe oro ija tabi ijangbon kan nwa o bo, maa sora ki o si lo kun fun opolopo adura ati suuru. 10Bi etelewo re otun ba n hun o pupo, mo daju pe iwo yoo ri owo tabi ohun ti yoo fa owo wa gba. 11Bi atelewo re osi ba nhun o pupo, mo daju pe oro inawo kan ti ko ni mu inu re dun nbo wa ba o, adura lebo onigbagbo. 12Bi inu re ba nhun o pupo, ki o mo pe a o pe o si ibi ase kan tabi ki won gbe ounje wa fun o. 13Bi orunkun re otun ba n hun o pupo, mo pe iwo yoo bo si ipo yuntun kan, yato si eyi ti o ti wa tele. Siwaju si I, igba rere kan nbowa fun o ati pelu pe iwo yoo wa je olusin Olorun ju ti atehinwa lo, nitori pe Emi Olrun yoo naa gbile ninu re, okan re yoo si maa poungbe oro Olorun. IRAWO RE PELU ISE ASELA RE